Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekoo ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun meji kan lagbegbe Lekki nipinlẹ naa.
Ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ti wọn pe ni Rapid Response Squad (RRS) la gbọ pe o rọwọ to awọn meji naa l'Ọjọbọ, ọsẹ yii, ọjọ kẹtala, oṣu keji, ọdun 2025.
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa fi sita, wọn ni Okey Bright, ọmọ ọdun mọkanlelogun ti inagijẹ rẹ n jẹ “B in Fine Boy", ati Daniel Prince, ọmọ ọdun mejilelogun.
Atẹjade ọhun sọ pe nnkan bi agogo mẹrin oru ọjọ Aje, ọjọ kẹrinla, oṣu kinni lọwọ tẹ awọn mejeeji lasiko ti wọn n bọ lati ode ẹgbẹ okunkun wọn, eyi to waye ni otẹẹli kan niluu Lekki.
“Iwadii fi han pe agbegbe Ikoyi ni Bright n gbe, ọdun 2024 lo si darapọ mọ ẹgbẹ okunkun, koda akẹkọọ fasiti ni pẹlu,” atẹjade ọhun ṣalaye.
“Prince, ti wọn pe ni “Rugged Promotion”, lo jẹ aṣerunloge, bẹẹ lo tun jẹ akẹkoọ fasiti.”
Siwaju sii ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe irin wọn to mu ifura dani pẹlu bi Daniel Prince, ṣe gbe baagi ikọpa dani.
Ọlọpaa ni inu baagi ti Prince gbe dani ni wọn ba fila ẹgbẹ okunkun nibẹ, ti ọwọ si tẹ awọn mejeeji.
Bẹẹ ni wọn lawọn ti fa wọn le awọn ọlọpaa ọga wọn lọwọ lati ṣewadi wọn siwaju sii.
No comments:
Post a Comment