Awọn alakoso fasiti Nnamdi Azikiwe to wa niluu Awka, ipinlẹ Anambra danu, ti wọn si lawọn ko fẹẹ ri lagbegbe ati ayika ile ẹkọ naa mọ.
Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrinla, oṣu Keji, ọdun 2025 ni awọn alakoso naa jawe gbele ẹ fun akẹkọbinrin naa, Goddy-Mbakwe Chimamaka Precious.
Ninu atẹjade ti adele alakoso eto igbaniwọle ni fasiti naa, Victor Modebelu fi sita, wọn ni o ṣe dandan lati le Precious dani lori iwa ailẹkọ to hu naa.
Bakan naa ni wọn sọ pe igbesẹ ọhun lo waye lẹyin abajade igbimọ oluwadii ti wọn gbe dide lati ṣewadi ohun to ṣokunfa aawọ laaarin Precious ati olukọ naa, eyi ti fọnran rẹ kaakiri ori ayelujara laipẹ yii.
No comments:
Post a Comment