Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba orileede Naijiria tẹlẹ, Sẹnetọ Bukola Saraki ni iroyin ti fi to wa leti pe yoo foju ba ile-ẹjọ lori ẹsun ibanilorukọjẹ lọjọ Aje, Mọnde ọsẹ tuntun yii, ọjọ kẹwaa, oṣu Keji, ọdun 2025.
Ninu ẹsun ti nọmba rẹ jẹ 9/4483/24, la gbọ pe Saraki yoo ti jẹri tako amugbalẹgbẹ agba pataki fun gomina ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Olayinka Fafoluyi tọpọ awọn eeyan mọ si Solace niwaju ile ẹjọ giga to wa niluu FCT, Abuja.
Saraki lo fẹsun ibanilorukọjẹ kan Fafoluyi niwaju ile ẹjọ naa.
Aṣofin agba tẹlẹ naa fẹsun kan Solace wi pe o ba oun lorukọ jẹ pẹlu ohun to kọ soju opo ayelujara, lori tọọgi PDP kan, Ojulari tọwọ tẹ.
Ojulari lọwọ tẹ pẹlu ibọn lasiko ipolongo idibo ti adije sipo ile igbimọ aṣoju-ṣofin lẹgbẹ oṣelu PDP ṣe lasiko eto idibo apapọ ọdun 2023.
Saraki sọ pe bi Solace ṣe sọ pe Ojulari jẹ ọmọ ẹyin to n ṣiṣẹ foun jẹ ibanilorukọjẹ ti ko ṣee gboju fo da, to si n rọ ile ẹjọ lati paṣẹ fun Solace lati pa ọrọ to kọ naa rẹ, tabi ko lọ san biliọnu mẹwaa naira gẹgẹ bi owo itanran.
Solace funra rẹ ṣaaju asiko yii ti sọ niwaju ile ẹjọ wi pe oun ko jẹbi, to si jẹ ko di mimọ pe gbajugbaja tọọgi to n ṣiṣẹ fẹgbẹ PDP ni Ojulari, ẹni ti Saraki jẹ adari rẹ.
A gbọ pe ofin gba Saraki laaye lati yọju sile ẹjọ funra rẹ, ko si ṣalaye bi ọrọ ti Solace kọ naa ṣe ba orukọ rẹ jẹ.
No comments:
Post a Comment