Bi awọn dokita ati awọn oṣiṣẹ eleto ilera lorileede Naijiria ṣe n filu silẹ lọ si oke okun lati lọ ṣiṣẹ, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti wa ọna abayọ tuntun lati fa oju awọn eleto ilera mọra, lati dẹkun jijapa.
Nipinlẹ Kwara, gomina ipinlẹ naa n ṣe itọju awọn oṣiṣẹ bo ti tọ ati bo ti yẹ.
Eto igbayegbadun awọn araalu, paapaa awọn oṣiṣẹ jẹ ijọba Kwara logun gidigidi, leyi to jẹ ki wọn mu ọrọ wọn lọkunkundun.
Ninu atẹjade ti oluranlọwọ pataki fun gomina lori iroyin igbalode, Olayinka Fafoluyi fi sita, o ṣalaye diẹ lara awọn igbesẹ ti kii jẹ ki awọn oṣiṣẹ eleto ilera Japa bi ti awọn ipinlẹ yooku ni Naijiria.
Fafoluyi sọ pe laipẹ yii ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq pin awọn aṣọ iṣẹ igbalode fun awọn agbẹbi ti ko din ni ẹgbẹrun mẹwaa.
O ni lara awọn ifilọlẹ ti iyawo Aarẹ Tinubu, Sẹnetọ Olurẹmi Tinubu wa ṣe nigba to yọju si ipinlẹ Kwara laipẹ yii niyẹn.
Ọkunrin naa jẹ ko di mimọ pe gbogbo ohun ti ko nii jẹ ki awọn oṣiṣẹ eleto ilera ronu lati fi iṣẹ silẹ lọ si orileede miran ni ijọba Kwara n ṣe.
Bẹẹ lo ni loorekoore ni ijọba n gba awọn oṣiṣẹ eleto ilera sẹnu iṣẹ, bẹẹ ni wọn tun buwọ lu ida ọgọrun owo oṣu fun awọn dokita ati oṣiṣẹ eleto ilera, eyi ti wọn pe ni Consolidated Medical Salary Structure (CONMESS) ati Consolidated Health Salary Structure (CONHESS).
Siwaju sii lo ni ijọba ti yi awọn ile iwosan jẹnẹra pada si tawọn olukọni, nibi ti wọn ti n kọ awọn akọṣẹmọṣẹ ọjọgbọn jade.
"Gẹgẹ bi Gomina AbdulRazaq ṣe sọ, wọn ti sọ ile iwosan jẹnẹra tiluu Ilorin di ti awọn olukọni, iyẹn Kwara State University Teaching Hospital; ile iwosan jẹnẹra ti Omu-Aran di Thomas Adewunmi University Teaching Hospital; ati Sobi Specialist Hospital di Al-Hikmah University Teaching Hospital (lori ajọṣepọ adehun).
"Gomina to tun jẹ ko di mimọ oe oun n woye lati sọ ile iwosan jẹnẹra ti Offa di eyi ti wọn yoo fi maa ṣe idanilẹkọọ, nibi ti awọn alakoso Kwara State Hospitals Management Board yoo ti maa kọ awọn akẹkọọ ile ẹkọ Bartholomew College of Nursing."
Lakotan , o jẹ ko di mimọ pe ile ẹkọ alaja rẹpẹtẹ ti Sẹnetọ Oluremi Tinubu ti bẹrẹ lagbegbe GRA
No comments:
Post a Comment