Gbajugbaja onkọrin takasufee to jẹ obinrin nni, Temilade Openiyi, tọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Tems, ti sọ pe bo tilẹ jẹ pe oun fi ọpẹ fun Ọlọrun lori aami ẹyẹ agbaye ti Grammy toun gba laipẹ yii, sibẹ, oun ko tun ni ṣai mọ riri mama oun.
Tems sọ pe oun ni ibaṣepọ to dan mọnran daadaa pẹlu mama oun, ati pe ko si nnkan toun le fi pamọ fun mama oun.
Onkọrinbinrin naa sọ pe ko si aṣiri kankan toun le fi bo fun mama oun, nitori pe bii ibeji lawọn ṣe ri.
Tems sọrọ naa nibi ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ET lasiko ti eto aami ẹyẹ naa, ẹlẹẹkẹtadinlaadọrin iru ẹ to waye niluu Los Angeles lọjọ Aiku to kọja.
“Oun [Iya mi] nikan ni mo ni. Ko si ohun kan ti mo le fi pamọ fun un,” Tems sọ bẹẹ.
Nigba to n sọrọ lori aami ẹyẹ agbaye naa, Tems jẹ ko di mimọ pe: “Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun. Mo dupẹ gidigidi. Mo ro pe ibunkun nla leyi jẹ. Ọlọrun bukun fun mi, o si mu mi tayọ. Mo kan fẹẹ sọ eyi bi mo ṣe le sọ ọ ni.”
No comments:
Post a Comment