Ẹ wa gbọ ohun ti Gomina Sanwo-Olu sọ nipa AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, February 5, 2025

Ẹ wa gbọ ohun ti Gomina Sanwo-Olu sọ nipa AbdulRazaq


Gomina Babajide Sanwo-Olu tipinlẹ Eko ti ṣapejuwe akẹgbẹ rẹ lati ipinlẹ Kwara, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq gẹgẹ bi aṣaaju rere to ṣee fọkan tan.
 
Ninu atẹjade ti Sanwo-Olu fi ki AbdulRahman AbdulRazaq, ẹni to tun jẹ alaga igbimọ awọn gomina lorileede Naijiria lonii tii ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun marundinlaadọrin.
 
“Gomina AbdulRazaq ti fi ara rẹ han gẹgẹ bi aṣaaju to ṣee fọkan tan, ẹni ti ko ni iwa imọ-tara-ẹni nikan, to si fi ara jin, nipa mimu agbelarugẹ ba eto iṣejọba awa-ara-wa si gbogbo olugbe ipinlẹ Kwara ati Naijiria lapapọ.

“Lorukọ iyawo mi, Ibijoke, ijọba wa ati gbogbo ọmọ ipinlẹ Eko, mo darapọ mọ awọn ẹbi, ọrẹ, awọn alabaṣiṣẹpọ ninu oṣelu ati ipinlẹ Kwara lati ṣayẹyẹ fun Gomina Abdulrahman AbdulRazaq.


“Pẹlu aṣeyọri nla yii ni ọdun marundinlaadọrin rẹ, mo n fẹ ilera pipe ati ẹmi gigun fun alaga wa. Mo gbadura pe ọlọrun yoo tubọ maa fun un ni oku ati agbara lati tubọ maa ṣiṣẹ isin ọmọniyan, ipinlẹ Kwara ati Naijiria.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI