Ẹgbe gomina nilẹ Naijiria, iyẹn Nigeria Governors’ Forum (NGF) ti kọminu gidi lori iṣẹlẹ ikọlu to ṣẹlẹ lawọn agbegbe kan nipinlẹ Plateau, eyi to mu ẹmi ọpọ eeyan lọ, tawọn miran si farapa yannayanna.
Ẹgbẹ gomina naa wa ba ijọba, araalu, paapaa awọn idile ti iṣẹlẹ naa kan kẹdun.
Ninu atẹjade ti alaga ẹgbẹ naa, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara fi sita, o ni ẹdun ọkan lo jẹ pe asiko ti ipinlẹ Plateau n gbadun alaafia ati iṣọkan nipasẹ igbiyanju ijọba awọn ọba alade ati awọn olori ni ijamba naa wọle de.
O wa gbadura fun ipinlẹ naa ati awọn idile tọrọ naa kan wi pe iru rẹ ko tun ni ṣẹlẹ mọ.
No comments:
Post a Comment