Niṣe lọrọ bẹyin yọ laarọ oni, ọjọ Aje, ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹfa ọdun 2025 nigba ti wọn lawọn ọlọpaa lo ti ẹnu ọna abawọle ileeṣẹ ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party, PDP to wa niluu Abuja pa.
Oni lo yẹ ki ipade igbimọ iṣakoso, NEC ẹgbẹ naa waye, ṣugbọn ti wọn lawọn ọlọpaa ti duro digbi sibẹ pe ko sohun ti yoo ṣẹlẹ nibẹ.
Ọkan lara awọn alẹnulọrọ lẹgbẹ naa sọ fawọn akọroyin pe awọn ọlọpaa duro sẹnu ọna abawọle wọn lati da ipade ti wọn pe ni 'NEC Expanded Caucus Meeting' to fẹẹ waye duro
Bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa gba awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ẹgbẹ naa laaye lati wọle, ṣugbọn nigba to ya ni wọn le gbogbo wọn jade sita, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Bakan naa, gbogbo awọn akọroyin to wa lori iduro nibi iṣẹlẹ naa ni awọn ọlọpaa sọ fun lati kuro lagbegbe naa.
Ẹkunrẹrẹ nbọ laipẹ...
No comments:
Post a Comment