Ẹ fura ooo! Agbara omiyale nbọ laipẹ - Ijọba Kwara ṣekilọ fawọn araalu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, June 20, 2025

Ẹ fura ooo! Agbara omiyale nbọ laipẹ - Ijọba Kwara ṣekilọ fawọn araalu

Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ṣe ikilọ fun gbogbo araalu patapata lati wa ni ojufo nipa arọda ojo ti yoo fa agbara omiyale-agbara ya ṣọọbu.

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ to n ri sọrọ iṣẹ agbẹ ati ọgbin to fi mọ idagbasoke igberiko ti sita, sọ pe awọn araalu gbọdọ gbaradi fun omiyale to n bọ lọna.

Ileeṣẹ naa sọ pe ajọ to n ri sọrọ agbara to wa niluu Abuja, iyẹn National Flood Early Warning Systems Centre ti woye nipa ojo nla ti yoo rọ lọjọ diẹ si asiko yii kaakiri Naijiria.

Wọn ni bo tilẹ jẹ pe ajọ naa ti tọka awọn agbegbe ti arọda ojo ati omiyale yoo ti waye, eyi ti Jẹbba ati awọn agbegbe kan nijọba ibilẹ Moro wa lara wọn.

Wọn ni ewu nla lo n kan ilẹkun pẹlu bi ajọ naa ṣe ṣalaye, ti gbogbo araalu si gbọdọ gbaradi fun un.

"Ikilọ naa lọ ni ibamu pẹlu asiko ti ojo ti de gongo lati maa rọ, asiko ti a saba maa n ri ojo nla, agbara nla ati oniruru idiwọ," atẹjade naa sọ bẹẹ.

Siwaju sii ni wọn jẹ ko di mimọ pe niwọn igba ti ko ti si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ naa, ijọba wa n ṣe ikilọ wi pe ki awọn araalu ati ileeṣẹ tọrọ naa kan tete bẹrẹ sii gbe igbesẹ to yẹ ki asiko ọhun top de.

Wọn ni ki awọn to n gbe lawọn agbegbe ti ko jinna si odo ati agbegbe ti wọn maa n ni iriri omiyale tete wa ibomiiran ti wọn yoo lọ maa gbe.

Ki wọn maa ko ibi ti omi n gba kọja loorekoore, ko ma ba a kun ju.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI