Olukọ to ba pẹ de ile-ẹkọ yoo rugi oyin - Ijọba Kwara ṣekilọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, June 20, 2025

Olukọ to ba pẹ de ile-ẹkọ yoo rugi oyin - Ijọba Kwara ṣekilọ


Lojuna lati fopin si oniruuru iwa aibofinmu lẹnu iṣẹ, paapaa bi awọn olukọ ṣe n pẹ de ile-ẹkọ ni gbogbo igba, ati bawọn akẹkọọ ṣe n rin regberegbe kaakiri adugbo, ijọba ipinlẹ Kwara ti sọ pe gbogbo iwa naa yoo dopin.

Ijọba Kwara ni ikora-ẹni-nijanu gbọdọ wa kaakiri awọn ile-ẹkọ to wa nipinlẹ naa, ni ibamu pẹlu ilana eto ẹkọ lagbaye.

Kọmiṣanna feto ẹkọ, Ọmọwe Lawal Olohungbebe lo sọ eyi di mimọ lasiko to n ṣe ifilọlẹ igbimọ ti yoo maa gbogun ti awọn iwa naa.

Ọmọwe Olohungbebe ṣalaye pe ijọba nilo lati ri ọwọ iwa ibajẹ ti awọn eeyan, paapaa awọn oṣiṣẹ ti ri gẹgẹ bi nnkan to yẹ naa bọlẹ, ko si dohun igbagbe patapata.

O ni ọpọ awọn oṣiṣẹ, akẹkọọ ati olukọ ni wọn ko ri nmkan buburu ninu awọn adojutini ti wọn n hu kaakiri.

Ọmọwe Lawal Olohungbebe ni igbimọ naa ni yoo ri sọrọ awọn akẹkọọ ti wọn n rin regberegbe kaakiri adugbo lasiko ti eto ẹkọ n lọ lọwọ nile ẹkọ, ati bi awọn olukọ ṣe n pẹ de ile-ẹkọ tabi pe ki wọn ma yọju.

Igbesẹ tuntun yii ni Ọmọwe Olohungbebe sọ pe o lọ ninamu pẹlu agbekalẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lati mu ayipada rere wọ eto ẹkọ nipa dida ikora-ẹni-nijanu pada sipo.

O wa rọ awọn ọmọ igbimọ naa lati rio daju pe wọn ṣiṣẹ ti wọn gbe le wọn lọwọ l'ọna to yẹ lai ṣe ojusaaju ẹnikẹni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI