Ileeṣẹ to n ri si iṣẹ agbẹ ati ọgbin nipinlẹ Kwara ti jẹ ko di mimọ pe bi owo ounjẹ ṣe lọ silẹ kaakiri ipinlẹ naa ko ṣẹyin iṣẹ takuntakun ti Gomina AbdulRahman AbdulRazaq n ṣe lẹka iṣẹ agbẹ.
Kọmiṣanna feto iṣẹ agbẹ ati idagbasoke agbegbe, Afees Abolore Alabi lo fidi rẹ mulẹ nibi akanṣe eto idanilẹkọọ, ẹlẹẹkẹsab iru ẹ to waye ni fasiti ilu Ilorin.
Eto naa ti wọn pe akọle rẹ ni "Iṣẹ agbẹ ati eto aabo apapọ" (Agriculture and National Security: The Nigerian Armed Forces in Perspective,”) ni Ọjọgbọn Wahab Egbewole to jẹ giwa fasiti naa ti gba awọn eeyan lalejo.
Ọmọwe Abolore sọ pe gomina ṣe ifarajin ati iranlọwọ fun iṣẹ agbẹ, leyi to fa ki owo ounjẹ ja lọ silẹ fun irọrun araalu.
O ni iranlọwọ oorekoore ti gomina n ṣe fawọn agbẹ, kiko owo silẹ fun oniruuru eto idanilẹkọọ ati ibaṣepọ pẹlu awọn alẹnulọrọ lẹka iṣẹ agbẹ tun fa a.
Siwaju sii lo ni ipinlẹ naa ti n gbe igbesẹ lati bori iṣoro oko dida lasiko ọgbẹ ilẹ, leyi ti yoo tun jẹ ki ounjẹ pọ lasiko ti ojo ba kasẹ nilẹ.
O ni igbesẹ naa yoo pese aabo fun ounjẹ, yoo jẹ ki owo ounjẹ wa loju kan, yoo mu anfaani ere wọle.
No comments:
Post a Comment