Apapọ ẹgbẹ gomina lorileede Naijiria ti bu ẹnu atẹ lu ikọlu to waye nijọba ibilẹ Guma to wa nipinlẹ Benue.
Ninu atẹjade ti alaga ẹgbẹ naa, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara buwọ lu laipẹ yii, o ṣapejuwe ikọlu naa gẹgẹ bi iwa ọdaju to kọja sisọ.
Ẹgbẹ naa ba akẹgbẹ wọn, Gomina Hyacinth Iormem Alia ti ipinlẹ Benue ati gbogbo araalu kẹdun ikọlu ọhun.
Agbegbe Yelewata ati Daudu to wa nipinlẹ Guma ni awọn amookunṣeka ṣe ikọlu si, ti wọn si ọpọ araalu nibẹ.
Ẹgbẹ gomina ti wa gbadura fun gbogbo araalu, paaapa awọn tiṣẹlẹ naa kan wi pe Ọlọrun yoo wa pẹlu wọn.
Bẹẹ ni wọn ṣeleri pe digbi lawọn wa lẹyin gomina ati awọn araalu ipinlẹ naa.
No comments:
Post a Comment