Ọba Ọyatoye Titiloye, Oloro tiluu Oro fitan tuntun balẹ pẹlu ayẹyẹ 'Gbagede Ọba' - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, June 12, 2025

Ọba Ọyatoye Titiloye, Oloro tiluu Oro fitan tuntun balẹ pẹlu ayẹyẹ 'Gbagede Ọba'


Itan manigbagbe ni Ọba Joel Ọlaniyi Ọyatoye Titiloye, Olufayọ keji fi balẹ nibi ayẹyẹ ọdun Gbegede Ọba, akọkọ iru rẹ ti yoo waye niluu Oro, ijọba ibilẹ Irẹpọdun, ipinlẹ Kwara, pẹlu bo ṣe ṣiṣọ loju asia ọba ilu naa.

Ọjọ Aje, ọsẹ yii ni ayẹyẹ naa waye fun igba akọkọ, leyi to mu ki gbogbo ọmọ bibi ilu naa jakejado pada sile lati ṣayẹyẹ pẹlu ọba wọn, Ọba Joel Ọlaniyi Ọyatoye Titiloye, Olufayọ keji.

Ayẹyẹ ọhun ni wọn ṣagbekalẹ rẹ lati maa fi gbe aṣa ati iṣẹṣẹ ilu Oro larugẹ, ati lati pokiki ilu naa jakejado agbaye.

Lara awọn aṣa iṣẹmbaye to mu irẹpọ ati iṣọkan wọlu ilu naa ni ti afihan awọn onilu ibilẹ, onijo ibilẹ, egungun, awọn olorin ibilẹ, to fi mọ awọn miran.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, agbegbe mẹsan ọtọọtọ lo parapọ lati maa jẹ ilu Oro.

Yatọ si Alaafin Ọyọ to wa nibẹ, awọn alejo pataki to tun wa nibẹ ni Olorin Alaafin, Abiwumi Owoade; Olupo tiluu Ajaṣẹ Ipo; Olusin tiluu Iṣin; Awọn Ọyọmesi; Igbakeji gomina Kwara ti ọtunba Biọdun Ajiboye ṣoju fun; amugbalẹgbẹ pataki fun gomina ipinlẹ Eko lori eto igbokogbodo ọkọ, Toyin Arẹmu; Yinka Quadri; Ọjọgbọn Wale Sulaiman; Aṣoju ọba ilu Oro, Alaaji Taiwo Mustapha; Olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kwara ati awọn miran.

Nigba to n sọrọ, Ọba Ọyatoye jẹ ko di mimọ pe lati le tubọ ṣe igbelarugẹ fun aṣa ati iṣẹṣẹ ilu Oro lapapọ lo fa agbekalẹ Gbagede Ọba naa ti wọn yoo bẹrẹ sii ṣe.

Ọba Ọyatoye sọ pe Gbagede Ọba ni yoo rọpo Ojude Ọba ti awọn ọdọ ilu naa n ṣe tẹlẹ, nibi ti wọn yoo ti lọ ki kabiyesi lati gba adura lẹnu rẹ, leyi to ni wọn n ṣe tẹlẹ lọdọọdun.

‘‘Ala to wa si imuṣẹ ni eto Gbagede Ọba tiluu Oro yii jẹ, nitori pe igba akọkọ ree ti yoo waye. Erongba mi ni lati la oju awọn ọmọ ilẹ yii si aṣa, iṣe ati ohun ajogunba ilẹ wa,’’ Oloro sọ bẹẹ.

“Gbagede Ọba jẹ eto ti a gbe kalẹ lati ṣayẹyẹ aṣa ati iṣẹmbaye wa gẹgẹ bi ọmọ Yoruba ati Igbomina ti a jẹ.”

Kabiyesi wa dupẹ lọwọ gbogbo awọn alejo ti wọn fi asiko wọn silẹ lati wa ba wọn ṣayẹyẹ naa, to si ni eyi ni yoo jẹ ki ifẹ ati iṣọkan tubọ jọba laaarin gbogbo ọmọ Yoruba kaakiri agbaye.

Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti oludamọran pataki rẹ, Alaaji Salaudeen Sa’ad ṣoju fun gbe oriyin fun ọba alaye naa fun agbekalẹ tuntun naa, to si ni eto ti ko gbọdọ parun ni.

AbdulRazaq ni iyalẹnu nla lo jẹ pe laaarin asiko perete ti wọn fi ṣe ipalẹmọ eto naa, awọn eeyan dide lọpọ yanturu lati wa nibẹ, leyi to lo jọju, bẹẹ lo ṣeleri wi pe ijọba yoo tubọ maa ṣe iranwọ to ba yẹ fun igbelarugẹ aṣa ati iṣẹmbaye.

Nibi ayẹyẹ naa ni wọn ti fi asia Ọba Oloro tiluu Oro lelẹ, leyi ti yoo jẹ idanimọ kabiyesi, eyii si ni Alaafia Ọyọ, Ọba Akeem Abimbọla Owoade ṣiṣọ loju rẹ.

Iku Baba Yeye nigba to n fi imọriri rẹ han gbe oriyin fun Ọyatoye fun agbekalẹ tuntun to n jẹ ki ilẹ Yoruba tẹsiwaju, to si ni aṣa naa ko le parun lailai.

Kabiyesi ni ipinu to dara ni awọn ọmọ ilu naa ṣe lati yan Ọba Titiloye gẹgẹ bi Oloro tiluu Oro, to si ni aridaju ti wa pe ọba ti yoo pokiki ilu naa kaakiri agbaye ni wọn yan.

“Eeyan daradara ni Oloro, ẹni to ni ọkan rere si idagbasoke ilu yii. Mo ti mọ kabiyesi tipẹ, fun ọpọlọpọ ọdun nigba ti a wa ni Canada. Eeyan to dara ni, to si ni afojusun rere fun igbelarugẹ aṣa ati ohun ajogunba nilẹ Yoruba, leyi to lọ ni ibamu pẹlu afojusun emi naa,” Alaafin jẹ ko di mimọ.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI