Kwara sọ pe bi igbayegbadun araalu ṣe jẹ oun logun, naa ni eto imọtoto ṣe pataki
Kọmiṣanna feto ayika ati agbegbe, Hajia Nafisat Musa Buge lo sọrọ naa di mimọ lasiko to n bawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa ṣe ipade laipẹ yii.
Hajia Buge nigba to n kọminu lori bawọn eeyan ṣe n tapa si ofin ati ilana eto ayika, o ni awọn yoo too ṣagbekalẹ ile-ẹjọ alagbeeka sinu Ọja Ọba to wa niluu Ilorin.
O ni ile-ẹjọ naa ti wa tẹlẹ, ṣugbọn ti wọn ko lo o mọ, ṣugbọn ni bayii, awọn yoo gbe e dide pada fun araalu lati mọ pe ijọba ko fọwọ yẹpẹrẹ mu iwa idọti ayika mọ.
O ni ijọba ṣe n la kaka to lati rii pe ajakale arun buruku ko wọnu ilu, nipa jíjẹ ki gbogbo agbegbe wa ni imọtoto, sibẹ awọn araalu ko jẹ ki iṣẹ ijọba yọ.
No comments:
Post a Comment