Ile ẹjọ Majisireeti to wa niluu Ado-Ekiti ti paṣẹ pe ki awọn mejilelọgbọn kan ti wọn tapa si ofin ilana imọtoto eto ayika ati agbegbe nipinlẹ Ekiti lọ gba ilẹ oju opopona.
Onidajọ Olubunmi Bamidele to gbọ ẹjọ naa sọ pe gbogbo awọn eeyan naa ni wọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn ni ibamu pẹlu ofin to pe ni Ekiti State Environmental Health and Sanitation Laws.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọjọ Abamẹta to kọja yii ni eto gbale-gbata waye nipinlẹ naa, ṣugbọn ti wọn sọ pe ọwọ tẹ awọn kan ti wọn ko kopa.
Awọn mọkanlelogun ni ile ẹjọ fun ni anfaani lati san owo itanran, nigba ti awọn miran yoo ṣiṣẹ isin ilu ti wọn pe ni 'community service'.
Bakan naa ni ile ẹjọ naa da awọn mọkanla kan lare lẹyin agbeyẹwo to tọ.
No comments:
Post a Comment