Kwara gba ife ẹyẹ 'President’s Senior School Debate' - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, July 2, 2025

Kwara gba ife ẹyẹ 'President’s Senior School Debate'

Ipinlẹ Kwara tun ti fi itan tuntun balẹ pẹlu bi awọn akẹkọọ ipinlẹ naa ṣe gba ife ẹyẹ ifigagbaga ti ijiroro aarẹ, eyi ti wọn pe ni '2025 President's Senior School Debate Competition'.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, igba akọkọ ree ti ipinlẹ naa yoo de ipele aṣekagba lati gbegba oroke, iyẹn ti wọn yoo ṣe ipo kinni kaakiri ilẹ Naijiria.

Ifigagbaga yii lo jẹ ẹlẹẹkẹrindinlọgbọn iru rẹ ti yoo waye, eyi ti wọn ṣe nilui Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.

Ọpọ awọn ile ẹkọ to dangajia kaakiri ilẹ Naijiria ni wọn wa nibẹ lati figagbaga, to si jẹ pe awọn ile ẹkọ lati ipinlẹ Kwara ni bori.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ile ẹkọ lati ipinlẹ Rivers ni wọn kọju ile ẹkọ Kwara nipele aṣekagba.

Nigba to n gba awọn akẹkọọ naa lalejo ninu ọfiisi rẹ laipẹ yii, Kọmiṣanna feto ẹkọ, Ọmọwe Lawal Olohungbebe sọ pe bi kii ba a ṣe pe Gomina AbdulRahman AbdulRazaq fi ara jin lati mu idagbasoke ati ilọsiwaju ba eto ẹkọ ni, o ṣee ṣe ki aṣeyọri ọhun ma waye.

O ni ayipada ati atunto ti iṣakoso ipinlẹ naa mu ba igbe aye awọn olukọ ati agbegbe ikẹkọọ to dara lo ṣe iranwọ bi awọn akẹkọọ naa ṣe peregede.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI