Lọjọ Aje, Mọnde ọsẹ yii ni awọn agbaagba lẹka eto aabo wọ ilu Lafiagi lati pana rogbodiyan to n ṣẹlẹ nibẹ, ati lati fọkan awọn araalu balẹ wi pe alaafia yoo jọba.
Bi ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ni awọn ọdọ ti inu n bi yabo ileeṣẹ ajọ to n gbogun ti lilo egboogi oloro nilẹ Naijiria, NDLEA niluu Lafiagi, ti wọn si dana sun un kọja sisọ.
Ko si idi pataki meji ti wọn lo fa iṣẹlẹ yii, bi ko ṣe bawọn oṣiṣẹ NDLEA ṣe lọ yabo awọn eeyan, ti wọn si ko egboogi oloro ti wọn n ṣe okoowo rẹ.
A gbọ pe oriṣiriṣi wahala lo n koju ilu Lafiagi lati bi ọsẹ meloo sẹyin, leyi ti wọn lawọn eleto aabo n gbena woju awọn to n ta egboogi oloro.
Lara awọn agbaagba lẹka eto aabo ti wọn lọ siluu Lafiagi ni Kọmiṣanna ọlọpaa, Ojo Adekimi; Brigade Commander Brigadier General Ezra Barkins, ati amugbalẹgbẹ pataki fun gomina lori eto aabo, Alaaji Muhyideen Aliu.
Alaga ijọba ibilẹ Lafiagi, Abdullahi Bello; alakoso eto idagbasoke Esu, Alaaji Haruna Likpata; Kọmiṣanna f'ọrọ awọn ọdọ, Shehu Ndanusa Usman; ati alaga ileeṣẹ eto ẹkọ, Bello Taoheed Abubakar lo gba wọn lalejo.
"ifẹhonuhan to waye laarọ lo nii ṣe pẹlu awọn afurasi oniṣowo egboogi oloro ti ọwọ tẹ laipẹ yii. Awọn olufẹhonuhan lo anfaani kudiẹkudiẹ to wa ninu eto aabo lati ṣe ikọlu si ileeṣẹ NDLEA, nibi ti wọn ti dana sun ọkọ mẹta ati awọn ọkada alupupu, ti wọn si tun ji awọn nnkan ti wọn gba lọwọ awọn olokoowo egboogi oloro lọ. Wọn tun gbiyanju lati kọlu aafin Emir, nitori ti wọn sọ pe Emir ko da awọn NDLEA duro lati rọwọ to awọn olokoowo egboogi oloro ati awọn to n mu u," Alaaji Aliu sọ bẹẹ.
Aliu jẹ ko di mimọ pe iwa ọdaran gba a ni, ati pe awọn bu ẹnu atẹ lu iwa naa nitori pe o tako ofin aabo.
Bakan naa lo fidi rẹ mulẹ pe awọn ologun ati awọn ileeṣẹ eto aabo yooku ti da alaafia pada silu Lafiagi, ati pe awọn tun ti ṣabẹwo si aafin, ti awọn si ba awọn araalu sọrọ nibẹ.
No comments:
Post a Comment