Ẹ fura o! Arọda ojo omiyale n bọ laipẹ - Ijọba Kwara pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, July 30, 2025

Ẹ fura o! Arọda ojo omiyale n bọ laipẹ - Ijọba Kwara pariwo sita

Ijọba ipinlẹ Kwara ti ke gbajare sawọn araalu lati wa ni imurasilẹ arọda ojo ti yoo fa omiyale kaakiri ipinlẹ naa.

Wọn ni ọjọ naa yoo tun san ara nla ati iji lile, eyi to ṣee ṣe ko bẹrẹ pati oni, ọgbọn ọjọ, oṣu Keje, ọdun 2025.

Ijọba sọ pe ajọ to n ṣagbeyẹwo oju ọjọ nilẹ Naijiria, iyẹn Nigeria Meteorological Agency (NiMet) lo fi ikede naa sita.

Ninu atẹjade ti Agboola Olarewaju, to jẹ alakoso eto ilanilọyẹ nileeṣẹ to n ri sọrọ eto ikansira-ẹni fi sita, o rọ gbogbo awọn to n gbe nitosi odo lati kuro ko ojo naa too bẹrẹ, ko ma ba a ṣakoba fun wọn, nipa pipadanu ẹmi ati dukia.

"A rọ gbogbo araalu lati wa ni ikiyesara nipa ibi ti wọn ba n lọ, ati pe ki wọn ṣọra lati jade nigba ti ojo ba fẹẹ rọ," atẹjade naa sọ bẹẹ.

Bakan naa ni ijọba tun rọ awọn araalu lati pa gbogbo ina, tabi ki wọn yọ awọn ohun elo to n lo ina silẹ nigba ti wọn ba kofiri wi pe ojo fẹẹ rọ, tabi ti wọn ba fẹẹ jade.

"Lati le dẹkun omiyale ati pipadanu ẹmi ati dukia, ijọba ti bẹrẹ sii gbẹ odo Asa, nigba ti ileeṣẹ to n ri sọrọ eto ayika naa ti bẹrẹ sii ko idọti kuro l'awọn oju ọna ti omi n gba kọja," ijọba tẹsiwaju.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI