Aarẹ Tinubu da agunbanirọ mẹjọ lati Kwara lọla, Gomina AbdulRazaq fidunnu han - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, July 30, 2025

Aarẹ Tinubu da agunbanirọ mẹjọ lati Kwara lọla, Gomina AbdulRazaq fidunnu han


Gomina AbdulRahman Abdulrazaq tipinlẹ Kwara ti fi idunnu rẹ han si Aarẹ Bola Ahmed Tinubu lori bo ṣe da awọn agunbanirọ mẹjọ lati ipinlẹ naa lọla.

Awọn mẹjọ naa lo wa lara awọn agunbanirọ igba ti wọn ṣe daadaa julọ, eyi ti Aarẹ Tinubu da lọla

Awọn agunbanirọ mẹjọ naa ni: Kareem Jeelel Amoloye; Adebiyi Lekan Hamzat; Aminat Ajoke Hassan; Alabi Omotayo; Lawal Victor; Lawal Oluwatobi; James Peninah; ati Israel Ayeni. 

Nigba to n fi idunnu rẹ han, o gbe oriyin fun iṣẹ isin ilẹ baba wọn ti wọn ṣe lọna iwuri.

O jẹ ko di mimọ pe ko sohun to lọ lai jẹ pe awọn kan n woye, leyi to jẹ awokọṣe fawọn to n bọ lati tọpasẹ iwa ikora-ẹni-nijanu ati itẹpamọṣẹ.

AbdulRazaq to dupẹ lọwọ awọn to gba aami ẹyẹ naa lori bi wọn ṣe jẹ aṣoju rere to gbe orukọ ipinlẹ naa ati mọlẹbi wọn larugẹ, lo lu wọn lọgọ ẹnu lati tubọ tẹsiwaju aṣeyọri naa, pẹlu bi wọn ṣe gba iṣẹ tuntun lati ọdọ ijọba apapọ nipasẹ Aarẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI