Gomina AbdulRazaq ṣe koriya miliọnu kan naira fawọn akẹkọọ to peregede ninu idije to waye l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, July 5, 2025

Gomina AbdulRazaq ṣe koriya miliọnu kan naira fawọn akẹkọọ to peregede ninu idije to waye l'Abẹokuta


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara ti gbe oṣuba kare fawọn akẹkọọ ipinlẹ naa to peregede julọ nibi idije ifigagbaga awọn akẹkọọ to waye niluu Abẹokuta ipinlẹ Ogun laipẹ yii.

AbdulRazaq sọ pe idunnu nla lo jẹ foun wi pe awọn akẹkọọ naa tun polongo ipinlẹ Kwara lara ọtọ, to si mu ori oun wu.

Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe aṣeyọri yii lo fidi ipa ribiribi ti iṣakoso oun n ko lori idagbasoke ati ilọsiwaju eto ẹkọ nipinlẹ naa mulẹ.

Gomina AbdulRazaq sọrọ naa niluu Ilọrin lasiko to n gba ikọ akẹkọọ naa ati awọn adari wọn lalejo ni ọfiisi rẹ.

Nibẹ ni gomina ti sọ pe lati fun awọn akẹkọọ naa ni koriya, oun yoo fun akẹkọọ kọọkan ni miliọnu kan naira, bẹẹ ni awọn adari wọn naa ni idaji miliọnu kan naira, ẹnikọọkan, nitori pe iwuri nla lo jẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI