Gbajugbaja olowo agbaye nni, Elon Musk ti kede idasilẹ ẹgbẹ oṣelu tuntun nilẹ Amẹrika, eyi to pe ni 'Amerika Party', to si lo ṣe pataki lati da ẹgbẹ oṣelu miran silẹ.
Alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ 'X' naa sọ pe ẹgbẹ oṣelu tuntun yii yoo da ogo ilẹ Amẹrika pada, bi awọn araalu ba gba a wọle.
Ọjọ Abamẹta to kọja yii ni Trump fi ikede naa sita, lati tako ọga rẹ tẹlẹ, Donald Trump to jẹ Aarẹ ilẹ Amẹrika.
Musk to tun ni ileeṣẹ Tesla jẹ ko di mimọ pe agbekalẹ eto owo ori ti Trump gbe kalẹ yoo ran ilẹ Amẹrika lọ soko gbese.
Bi ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ni Musk beere lọwọ awọn ololufẹ rẹ lori ikanni 'X' lati mọ boya wọn faramọ ẹgbẹ oṣelu tuntun.
Ṣugbọn nigba to n kede loju opo rẹ, lọjọ Satide, o sọ pe, “Lonii, a ti da ẹgbẹ oṣelu Amẹrika silẹ lati da ominira yin pada.”
O tun kọ ọ pe, “Nipa eeki si ookan, ẹ fẹ ẹgbẹ oṣelu tuntun, ati pe ẹ maa ri i!
“Bi a ba n sọ nipa ki wọn wa orileede wa lọ soko gbese, a n gbe ninu iṣakoso ẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo, kii ṣe oṣelu awa-ara-wa.
“Lonii, a ti ṣagbekalẹ ẹgbẹ oṣelu Amẹrika lati da ominira yin pada.”
No comments:
Post a Comment