Ileeṣẹ Lafarge gbarada lẹka eto ipawowọle fun saa keji ọdun 2025 - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, July 24, 2025

Ileeṣẹ Lafarge gbarada lẹka eto ipawowọle fun saa keji ọdun 2025

Awọn alakoso ileeṣẹ simẹnti to gbajumọ daadaa laagbaye, iyẹn Lafarge Africa PLC ti jẹ ko di mimọ pe ere nla lawọn jẹ saa keji ọdun 2025 ti a wa yii.

Wọn ni ida aadọrin ni ere ti wọn jẹ ni saa keji ọdun yii si ti eyi ti wọn jẹ ni saa akọkọ, eleyi ti wọn ni ko wọpọ latigba ti wọn ti da ileeṣẹ naa silẹ.

Ọtadinlọgọjọ biliọnu naira, N157.80b ni owo ti wọn pa ni saa keji ọdun to kọja, leyi ti tọdun yii si le ni ida aadọrin, to fi jẹ pe N268.63b ni wọn jeere rẹ.

A gbọ pe owo naa lo le ni Biliọnu mẹrinlelọgọrin naira ni owo ti wọn sọ pe o le si eyi ti wọn ti pa wọle tẹlẹ, ti apapọ rẹ si jẹ N268.63b.

Nigba to n sọrọ, Lolu Alade-Akinyẹmi to jẹ alakoso agba ileeṣẹ naa, o ni ‘‘Nigba ti a n ṣagbeyẹwo saa akọkọ, a rii pe awọn ikọ oṣiṣẹ wa n ṣiṣẹ takuntakun ni saa keji ọdun yii, ti wọn si jẹ ki ere ti a jẹ goke, nipa ifarajin wọn.

‘‘Aṣeyọri gidi la ṣe ni saa keji ọdun yii nigba ti apapọ owo to wọle le ni ida aadọrin, ti ere iṣẹ ti a jẹ le laadoje [153%], nigba ti ere owo ori si din diẹ ni ida ọtalenigba [248%].

“Mo dupẹ gidigidi lọwọ awọn oṣiṣẹ to n ṣiṣẹ lọsan ati oru, awọn onibara wa, to fi mọ awọn alẹnulọrọ ti wọn n ko ipa ribiribi lati gbaruku ti Lafarge Africa. Pẹlu gbogbo adojukọ ninu eto ọrọ aje layika, sibẹ, ifarajin ati iṣẹ takuntakun ti ẹ n ṣe lo n ro wa lagbara, to si n fun wa ni igboya.’’

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI