Ijọba ipinlẹ Ogun sọrọ lori awuyewuye ọmọ ikoko ti wọn ju sigbo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, July 24, 2025

Ijọba ipinlẹ Ogun sọrọ lori awuyewuye ọmọ ikoko ti wọn ju sigbo

L'Ọjọbọ tii ṣe Tọside, ọsẹ yii ni ijọba ipinlẹ Ogun pariwo sita wi pe ko si otitọ ninu iroyin ẹlẹjẹ ti wọn n gbe kaakiri wi pe ọmọ ikoko, ọmọ ọjọ meji to wa lakata ijọba ti dawati.

Kọmiṣanna fọrọ awọn obinrin ati awujọ nipinlẹ naa, Ọnarebu Adijat Adelẹyẹ ke gbajare naa wi pe ki ẹnikẹni ma ṣe gba iroyin ẹlẹjẹ naa gbọ, nitori pe erongba lati ṣi ọpọ awọn eeyan lọkan ni.

Laipẹ yii ni obinrin naa sọrọ lori ayelujara wi pe oun ri ọmọ ikoko he niluu Sayedẹrọ, ijọba ibilẹ Guusu Yewa, ati pe oun yoo gbe ọmọ naa lọ fawọn ijọba.

Ṣadede ni iroyin tun bẹrẹ sii lu ori ayelujara wi pe ọmọ naa ti di awati, nitori pe ko sẹni to le sọ bi ọmọ naa ti ṣe rin in.

Adelẹyẹ nigba to n sọrọ nibi ipade awọn akọroyin to waye niluu Abẹokuta, o ṣalaye pe ilana to tọ ni ijọba tọ lori ọmọ naa, lati le wa labẹ itọju to pe ye.

Kọmiṣanna naa sọ pe bi araalu ba ri ọmọ he, o ni eto ati ilana alakalẹ ti ijọba maa n gbe lati le jẹ ki ọmọ naa gba itọju to pe ye.

O sọ pe awọn ọlọpaa yoo ṣiṣẹ iwadii wọn, ko to di pe wọn fa iru ọmọ bẹẹ le ileeṣẹ wọn lọwọ lati gbe igbesẹ to ba ku, eyi to sọ pe o waye.

Adelẹyẹ sọ pe lẹyin ti obinrin naa fa ọmọ ikoko naa to jẹ ọkunrin le ijọba lọwọ tan, niṣe lo tun bẹrẹ sii lọ kaakiri lati maa beere fun iranlọwọ, to si loun ti na owo to to ẹgbẹrun lọna ọgọfa naira lori ọmọ naa lati fi tọju rẹ.

“O fun ọmọ naa lorukọ, o gẹ irun ori rẹ, o si gbe e lọ fun abẹrẹ ajẹsara ko to di pe o fa ọmọ naa le wa lọwọ,” Adelẹyẹ sọ bẹẹ.

O ni igbesẹ ti obinrin naa n gbe jẹ eyi to fi n wa oju aanu ti ko wulo lati ọdọ awọn araalu, ko le ri owo tu jọ funra rẹ.

“Gomina Dapọ Abiọdun lo n na owo lori ileeṣẹ yii, lai beere fun iranlọwọ araalu nipa itọju awọn ọmọde,” o ṣalaye siwaju.

Bakan naa lo ni awọn ọmọde ti wọn ba ti ri he ti di dukia ijọba, ati pe ẹni to ba ri ọmọ naa ko ni ojuṣe kankan lati ṣe mọ niwọn igba to ba ti fa a le ijọba lọwọ, ko si le sọ pe oun loun ni iru ọmọ bẹẹ labẹ ofin.

O sọ pe “Ẹ jẹ ki n sọ eyi daju fun un yin pe ojuṣe ijọba ipinlẹ Ogun lati maa tọju awọn ọmọde titi digba ojulowo obi wọn ba yọju sita.”

O wa ṣe ikilọ fawọn araalu lati ṣọra lori ọrọ ti wọn yoo maa sọ bi iru nnkan bayii ba ṣẹlẹ, nitori pe ijọba nikan lo ni ẹtọ lati ṣe ohun to tọ lori awọn ọmọ to ba wa lakata awọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI