Awọn alakoso agba ninu ijọ Aguda lorileede Naijiria, iyẹn 'The Church of Nigeria, Anglican Communion', ti paṣẹ pe opin deba gbogbo oloṣelu lati maa gun ori pẹpẹ ijọsin wọn lasiko ijọsin.
Igbesẹ yii lo waye lẹyin ti Minisita fun FCT, Nyesom Wike sọ awọn ọrọ alufanṣa sawọn oloṣelu ilẹ Naijiria lasiko to lọ ṣe ijẹri si awọn aṣeyọri rẹ lori ipo to di mu.
Bi ẹ ko ba gbagbe, lọsẹ to kọja lọhun ni Wike lọ si ẹka ijọ naa, St James Anglican Church to wa lagbegbe Asokoro niluu Abuja lati jẹri si agbara Ọlọrun to muu ṣe aṣeyọri nla gẹgẹ bi minisita fun FCT.
Nibẹ ni Wike ti sọ awọn ọrọ kungbakungbe si gbogbo awọn to pe ni ọta rẹ nidi oṣelu, ọrọ yii lo si da awuyewuye pupọ silẹ kaakiri Naijiria.
Ṣugbọn awọn alakoso ijọ naa ninu atẹjade ti alakoso agba ijọ naa, Most Revd Dr Henry Ndukuba, fi sita, o ni awọn nilo lati yago fun oṣelu ẹlẹyamẹya to le doju ilana wọn bolẹ.
O ni aṣẹ naa lo waye nibi ipade to pe ni Episcopal Consultatio, eyi to waye ni ẹka ijọ naa ti Nike to wa ni Ẹnugu.
Ijọ naa sọ pe bi awọn ba tẹsiwaju lati maa gba awọn oloṣelu laaye lati maa gun ori pẹpẹ ijọ, o le ṣe akoba fun awọn ohun ti wọn duro le lori, ati afojusun ile ologo ti wọn n le.
Bakan naa ni awọn alakoso yii tun fofin de awọn olori wọn lati maa gbe oriyin fun awọn oloṣelu lọna to le fa wahala fun ijọ wọn.
Siwaju sii lo fi kun ọrọ rẹ pe awọn oloṣelu ati aṣoju ijọba ni lati mọ pe ijọ kii ṣe ibi ti wọn ti le polongo erongba ọkan ọkan wọn, tabi lati maa sọ oniruuru ọrọ oṣelu to tako awọn oloṣelu ẹgbẹ wọn.
No comments:
Post a Comment