Bi kii ba a ṣe pe awọn ọlọpaa pajawiri ti a mọ si Rapid Respond Squard tete dide si iyale ile kan to fẹẹ bẹ sodo l'Ekoo, boya obinrin naa ko ba ti gbagbe pe oun wa saye ri.
Ori afara Carter to wa nipinlẹ Eko la gbọ pe awọn RRS ti kofiri iyale ile naa, lasiko to fẹẹ bẹ sii, ti wọn si sare doola ẹmi rẹ, iyẹn lọjọ kọkanla, oṣu keje, ọdun 2025.
Atẹjade ti ileeṣẹ naa fi sita lopin ọsẹ to kọja, wọn ni deedee agogo mejila kọja ogun iṣẹju ọsan ni awọn RRS kofiri obinrin naa, nibi to ti n gbiyanju lati bẹ sodo nla ọhun.
Loju ẹsẹ ti wọn ti mu la gbọ pe wọn ti lọ fa a le ọga wọn, Sọla Jẹjẹloye lọwọ, lati ni gbolohun pẹlu rẹ. Nibẹ ni wọn lobinrin naa ti ṣalaye ohun to n doju kọ nile ọkọ.
Lẹyin eyi ni wọn sọ pe ọga Jẹjẹloye ranṣẹ pe ọkọ ati ọmọ arabinrin naa, to si ba wọn yanju aawọ to wa laarin wọn, koda, ti wọn lo tun fun obinrin naa lowo lati tuu lọkan.
No comments:
Post a Comment