Awuyewuye yìí ló ń lọ káàkiri lórí àwọn Ìkànnì ìbánisọ̀rọ̀ lórí Ààrẹ àná, Muhammadu Bùhárì tí ó pa ipò dà láìpẹ́ yìí.
Àwọn kan sọ pé:
1.) Ẹlẹ́ṣẹ̀ ni Bùhárì nígbà ayé rẹ̀.
2.) Ẹ̀rù àtúbọ̀tán ń ba Bùhárì ṣáájú ikú.
3.) Ẹ̀rù ìyà inú kòtò ibojì òkú ń ba Muhammadu Bùhárì.
4.) Bùhárì fi ohùn sílẹ̀ pé kí wọ́n tọrọ àfonífojì lọ́wọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà fún òun tí òun bá ṣáájú aya òun kú.
5.) Ìyàwó Bùhárì ń tọrọ ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún un lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà.
Awo kan kò sí nínú awo ẹ̀pà. Irọ́ ńlá gbáà ni gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ yẹn...
Àwọn kan tilẹ̀ he ọ̀rọ̀ mọ́ Ààrẹ Bùhárì lẹ́nu pé ó sọ ọ́ nínú Fídíò kan pé kí wọ́n dárí ẹ̀ṣẹ̀ jin òun. Mo jẹ́ kí àwọn ènìyàn náà mọ̀ pé ọ̀tọ̀ ni ohun tí Ààrẹ Bùhárì ń wí nínú Fídíò náà, ìtumọ̀ ọ̀tọ̀ sì ni wọ́n ń fún ohun tí ó wí.
Àwọn kan tún béèrè lọ́wọ́ mi nígbà tí mo ṣàlàyé èyí fún wọn pé:
Kí ni ìdí tí Bùhárì fi sọ ní gbangba pé ipá òun kọ́ ló gbé òun dé ipò Ààrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà, èrú ló gbé òun dé ibẹ̀?
Mo jẹ́ kí ó yé wọn pé:
"Bùhárì kọ́ ló sọ èyí, Yar'adua ni.
Irọ́ funfun ni gbogbo ohun tí wọ́n ń wí lórí ẹ̀rọ-ayélujára jàre.
Ẹ má dá wọn lóhùn oo."
Lẹ́yìn èyí ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣíṣọ lójú Eégún ọ̀rọ̀ náà fún wọn pé:
"Nínú òfin gbogbo tó de jíjẹ́ Olórí ìlú, yálà ti ẹ̀sìn tàbí ti ayé, Bùhárì kò ṣẹ ẹnikẹ́ni oo.
Bí àwọn ènìyàn kan bá wá hu ìwà burúkú nígbà tí Bùhárì jẹ́ Ààrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà tí ó sì mọ̀ wọ́n láìmọ ohun tí ó lè ṣe fún wọn fún àwọn ìdí kan, òun kọ́ ló ni ẹ̀ṣẹ̀, àwọn tí wọ́n hu ìwà burúkú yẹn ló ni ẹ̀ṣẹ̀ oo."
Àwọn kan tún béèrè nípa ohun tí ó wà nínú Fídíò tí Bùhárì tí sọ pé:
"... whoever thought that there has been some forms of injustice on him, we are all humans. There is no doubt I hurts some people and I wish they would pardon me. And those who think I hurt them so much, please pardon me. I thank you so much."
(...gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ pé a ti hu ìwà kan láti fi ẹ̀tọ́ wọn dùn wọ́n, ènìyàn ni gbogbo wa. Ohun tí ó dájú ni pé, n óò ti mú inú bí àwọn kan lọ́nà kan tàbí òmíràn, kí wọ́n dárí jì wá. Bákan náà ni àwọn tí wọ́n bá lérò pé mo ti mú inú bí àwọn gidi gan-an, ó wù mí kí wọ́n gbìyànjú láti fi iyè dénú. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín gidi.)
ṣé kì í ṣe ẹ̀rù àtúbọ̀tán ló ń bà á tàbí ó ń ronú ọjọ́ àtisùn?
Èsì tí mo fún wọn ni pé:
"Èyí yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ tí ayé ń sọ kiri.
Kò sí ènìyàn rere tí kò ní lè wí irúfẹ́ ohun tí ó wí yìí.
Ẹ jẹ́ kí a gbé ọ̀rọ̀ náà kalẹ̀ bí ó ti yẹ.
Ojú tí àwọn ènìyàn fẹ́ kí a máa fi wo ọ̀rọ̀ náà ni pé, Bùhárì hu ìwà búburú nígbà tí ó wà ní ayé, kò sì fẹ́ kí Ọlọ́run fi ìyà jẹ òun... Ǹjẹ́ bẹ́ẹ̀ ló rí nínú ìwà, àṣà, ìṣesí, ipa, ipò àti akitiyan ọkùnrin náà nínú ìrìn-àjò ayé rẹ̀ tí ó fi ara hàn sí wa*🤷♂️❓❓🤷♂️🤷♂️💁♂️"
Ìbéèrè mi nínú gbólóhùn òkè yìí láti mọ̀ bí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀ ni ó mú mi sọ pé:
"Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ó léwu, ṣùgbọ́n bẹ́ẹ̀ kọ́ ló rí.
Ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn ni ó sún Bùhárì dé abala ibi tí ó hùwà sí yẹn.
Nínú gbogbo ohun tí a bá ń ṣe, ti Ọlọ́run nìkan ni kí a jẹ́ kí ó jù lọ.
Bùhárì kò fẹ́ kí àwọn ènìyàn kan ti òun kọjá ààyè láti ṣe ohun tí kò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe. Irúfẹ́ àwọn ènìyàn tí ń tì í láti hu ìwà ìbàjẹ́ yẹn gan-an ni Bùhárì gbàgbọ́ pé òun ṣẹ̀, kò rí i gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ níwájú Ọlọ́run Ọba.
Ẹni tí ó bá mọ̀ nípa ẹ̀sìn Ìsìláàmù tí Bùhárì ń sìn dáadáa, yóò mọ ìdí tí Bùhárì fi ń hùwà tí ń hù náà.
Ohun tí ó kàn ṣẹlẹ̀ ni pé kò sí ẹ̀dá tí yóò hu irúfẹ́ ìwà bẹ́ẹ̀ ní Nàìjíríà yìí, pàápàá láàrin àwọn Òṣèlú... Ẹni náà yóò máa kọsẹ̀ lára àwọn Òṣèlú náà ni...Àwọn tí Bùhárì ṣe àkíyèsí pé inú ń bí lórí àìgba ìmọ̀ràn wọn láti máa hu ìwà ìbàjẹ́ ni ó gbà pé òun ṣẹ̀, kì í ṣe Ọlọ́run ni Bùhárì ń wí, kì í sì í ṣe àwa ọmọ Nàìjíríà rere ló ń sọ
Ìtumò tí ẹ gbọ́dọ̀ fún àwọn gbólóhùn náà nìyẹn, kì í ṣe pé ó ń bẹ̀rù ẹ̀sẹ̀ burúkú kan tí ó ṣẹ̀ ní ìkọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run yóò fi ìyà jẹ òun lọ́run.
Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn òṣèlú yẹn dá sí i lọ́run ni Bùhárì ń wí.
Nínú ẹ̀sìn Ìsìláàmù, Ànọ́bì Muhammadu (SAW) ni ó hu irú ìwà yẹn nítorí kò fẹ́ kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun hu ìwà burúkú tí yóò já sí ẹ̀ṣẹ̀ sí Ọlọ́run nítorí òun. Ó gbìyànjú láti kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ bí a ti ń sá fún ẹ̀ṣẹ̀ àti bí a ti gbọ́dọ̀ dúró lórí òdodo bí ó ti wù kí àwọn ènìyàn kan máa tì wá láti dá ẹ̀ṣẹ̀ náà... A gbọ́dọ̀ dúró lórí òdodo títí dé ipò ikú...
Ìyàwó Bùhárì tí wọ́n wí, ohun tí ọkọ rẹ̀ ń wí kò yé òun gan-an... Ọkọ rẹ̀ kò sọ fún un pé òun dá ẹ̀ṣẹ̀ síwájú Ọlọ́run, àwọn agbọ̀ràndùn ló fẹ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà kọjá bí ó ti yẹ."
Bùhárì kò ṣẹ̀ yín, ẹ̀yin ni kí ẹ gbìyànjú láti tún ìwà yín ṣe gẹ́gẹ́ bí ọmọ Nàìjíríà, kí ẹ yé ṣẹ Ọlọ́run lára àwọn Adarí yín. Gbogbo èébú, èpè, ìwà ìkà àti ọ̀tẹ̀ tí ẹ máa ń hù sí àwọn Adarí yín, ẹ gbìyànjú láti jáwọ́, kí ojú yín lè là láti mọ ìgbà tí Ọlọ́run yóò rán Adarí rere sí yín.
Ẹ ṣeun oo.
© Ọ̀mọ̀wé ÌṢỌ̀LÁ Sauban Àlàdé Orí-Àrán
No comments:
Post a Comment