Aarẹ Adetọla, alaṣẹ Adron Homes kẹdun iku Awujalẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, July 15, 2025

Aarẹ Adetọla, alaṣẹ Adron Homes kẹdun iku Awujalẹ


Alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited, Aare Adetola EmmanuelKing ti ṣapejuwe Awujalẹ tilẹ Ijẹbu to waja, Ọba Sikiru Kayọde Adetọna gẹgẹ bi igi nla to wo nigbo.

O ni lara awọn agba igbaani ti wọn n ri lasiko yii lo poora lojiji, to si ni ibanujẹ nla ni iku rẹ jẹ fun gbogbo Akilẹ Ijẹbu ati orileede Naijiria lapapọ.

Ninu atẹjade ibanikẹdun to fi sita lọjọ Iṣẹgun oni, Aarẹ EmmanuelKing gbe oriyin fun ipa rere ti kabiyesi naa ko titi d'ọjọ ogbo to faye silẹ.

"Ọba Adetọna, ẹni to ku lẹni ọdun mọkanlelaadọrun, jọba fun ọdun marundinlaadọrin lara ọtọ, leyi to mu ko jẹ ọba to pẹ lori itẹ julọ ninu itan ilẹ Naijiria," Aarẹ EmmanuelKing sọ eyi ninu atẹjade rẹ.

"Ijọba rẹ kii ṣe wi pe wọn mọ-ọn si wi pe o pẹ nikan, bi ko ṣe pe o tun ko ipa ribiribi ninu eto aṣa ati iṣẹṣe, igbe aye ati igbelarugẹ eto ọrọ aje nilẹ Ijẹbu."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI