Ko din ni afurasi ọdaran ti wọn jẹ ohun ni wọn ti wa lahamọ awọn ẹṣọ ologun nipinlẹ Kwara lasiko ti a pari akojọpọ iroyin yii.
Bi ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ṣepade pẹlu awọn ọga ologun nipinlẹ naa, nipa bi alaafia yoo ṣe jọba pads lawọn agbegbe bii Ifelodun, Patigi ati Edu.
Lati bi oṣu meloo sẹyin ni awọn amookunṣeka ti n ṣọṣẹ lawọn agbegbe yii, to si jẹ pe bi wọn ṣe n ji awọn eeyan gbe, naa ni wọn n payan danu, pẹlu oniruuru iwa ọdaran miran.
Eyi lo mu ki ileeṣẹ ologun gbe ikọ ọmọ ogun irinwo dide, nipa iranlọwọ gomina ipinlẹ Kwara ati oludamọran agba lori eto aabo, NSA.
Lara awọn ilu ti awọn oṣiṣẹ ologun naa ti n ṣiṣẹ ni Ifelodun, Ekiti, Edu ati Patigi, nibi t'awọn ọdaran ọhun fi ṣe buba.
A gbọ pe pupọ ninu awọn afurasi yii ni wọn jẹ ogbologbo ọdaran ti awọn oṣiṣẹ aabo ti n wa tipẹ, ti wọn si ti n ṣe iranwọ gidi fawọn ologun.
Ọpọ awọn tọwọ tẹ yii lọwọ palaba wọn segi lagbegbe Babanla nijọba ibilẹ Ifelodun
Mẹwaa ninu wọn la gbọ pe wọn ti gbe lọ siluu Abuja loju ẹsẹ pẹlu awọn nnkan ija oloro ti wọn gba lọwọ wọn.
No comments:
Post a Comment