Agba oṣere tiata ilẹ Naijiria nni, Yẹmi Ṣolade ti sọ pe gbogbo igba ni ẹri ọkan maa n jẹ oun, nigba toun ba n ranti ọjọ toun gba oṣere tiata akẹgbẹ oun, Afeez Owo Abiodun leti.
Yẹmi Ṣolade sọ pe inu to bi oun lọjọ naa, lo jẹ koun ṣiwa hu, to si loun maa n kabamọ wi pe iwa naa tọwọ oun ṣẹlẹ.
Siwaju sii lo jẹ ko di mimọ pe igba naa ti pẹ diẹ, ati pe oun ko le ranti ọdun naa mọ, ṣugbọn toun ko le gbagbe bi nnkan ṣe ṣẹlẹ lalẹ ọjọ naa.
Ninu ọrọ rẹ, Solade sọ pe iṣẹlẹ naa ti to ogun ọdun bayii, bo tilẹ jẹ pe odun loun ko le sọ ni pato.
“Ẹ jẹ ki n Toro idariji lọwọ Afeez Abiodun. Mo ti gba a leti ri. Oun ni alakoso itage fiimu ti a lọ ya lọdun naa - bo tilẹ jẹ pe nko le ranti ọdun to jẹ. A rinrin-ajo kuro lọ siluu to sunmọ Ibadan lati ya iṣẹ naa. Nigba ti a pari, ti a si pada de, gbogbo ibi ti a n lo ti dọti kọja sisọ.
“Gẹgẹ bi alakoso fiimu, o bẹrẹ sii fi ẹsun kan awọn kan, eleyi si jẹ ki inu mi ru, to si jẹ ki n binu. Lai mọ, ninu okunkun, mo gba eti ẹ lọjọ naa - iṣẹlẹ ti mo kabamọ. Lọjọ keji, o ti tete kuro ni lokeṣan laarọ, nigba ti mo maa ji, o ti lọ.
“Afeez dakun, ma binu si mi.
“O ti pẹ gan-an, ki n sọ pe ogun ọdun. Mo ti sọ ọrọ yii fawọn eeyan tẹle, ṣugbọn mo kan fẹẹ sọ fun Afeez funra rẹ ni. Emi naa ko fẹran ki wọn sọrọ buruku si mi nita gbangba mo si gba wi pe ibi ti mo ku si ree.”
No comments:
Post a Comment