Opin de b'awọn to n sapamọ sinu igbo fi huwa ọdaran ni Kwara - Ileeṣẹ ologun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, July 11, 2025

Opin de b'awọn to n sapamọ sinu igbo fi huwa ọdaran ni Kwara - Ileeṣẹ ologun

.
Ileeṣẹ ologun ilẹ Naijiria, ẹka tipinlẹ Kwara ti sọ pe awọn yoo gba iṣẹ eto aabo ṣe lawọn inu igbo t'awọn amookunṣeka n lo lati fi ṣọṣẹ, iyẹn lawọn ijọba ibilẹ bii Edu ati Ifelodun.

Ṣaaju asiko yii ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ṣalaye awọn ohun to n ṣẹlẹ lagbegbe Lafiagi nijọba ibilẹ Ariwa Kwara, nipa ipenija to n doju kọ eto aabo.

Ilu Ilorin tii ṣe olu-ilu ipinlẹ Kwara ni ipade ọhun ti waye laaarin gomina ati awọn alẹnulọrọ nidi iṣẹ eto aabo, to fi mọ awọn agbaagba labẹ aburada ẹgbẹ Lafiagi Descendants’ Development Union (LADDU) ti Ọmọwe Abdullahi Jibril Mohammed Lafiagi jẹ olori wọn.

Gomina sọ pe ọrọ eto aabo agbegbe naa n kọ oun lominu gidi, pẹlu awọn araalu ṣe n laalaṣi

Ju gbogbo rẹ lọ, ileeṣẹ ti wa sọ fun ijọba ipinlẹ naa lati fọkan balẹ nitori gbogbo awọn to n sapamọ sinu igbo lati fi huwa ọdaran ni wọn yoo jẹ iyan wọn niṣu laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI