Lẹyin to wuye 'Akewejẹ', wọn tun f'oye tuntun da Fafoluyi, amugbalẹgbẹ pataki fun gomina Kwara lọla - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, August 13, 2025

Lẹyin to wuye 'Akewejẹ', wọn tun f'oye tuntun da Fafoluyi, amugbalẹgbẹ pataki fun gomina Kwara lọla


Oloko tiluu Oko-Irese, Alayeluwa, Ọba Victor Oluwafemi Olawuyi ti fi oye tuntun ti wọn pe ni Bọba Jiroro da amugbalẹgbẹ pataki fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara, Oloye Michael Olayinka Fafoluyi lọla, lori awọn ipa ribiribi to n ko laaarin ilu.
 
Ọba Olawuyi, Ilufẹmiloye, Adogunnibo akọkọ lo kede oye tuntun naa laipẹ yii, to si lẹni kan ṣoṣo ti ipo Aarẹ Bọbajiroro tọ si ni Fafoluyi tọpọ awọn eeyan tun n pe ni Solace.
 
Fafoluyi ni amugbalẹgbẹ pataki fun Gomina AbdulRazaq lori eto iroyin igbalode, ipo to di mu lati saa akọkọ iṣejọba gomina ọhun.
 
Ni nnkan bi oṣu meloo sẹyin ni Fafoluyi wuye oye 'Akewejẹ' tiluu Omu-Aran.
 
Gẹgẹ  bi a ṣe gbọ, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2025 ni eto ayẹyẹ iwuye naa yoo waye ni gbagede ile-ẹkọ Comprehensive to wa niluu Oko.
 
Ọba alaye naa sọ pe ko si idi meji toun fi fun Olayinka Fafoluyi loye naa, bi ko ṣe ti awọn ipa to jọju, eyi to n ko fun idagbasoke ilu, ati iwa ọmọluabi rẹ.

Kabiyesi ni kii ṣe lati fi ṣayẹyẹ aṣeyọri Fafoluyi nikan, bi ko ṣe lati tubọ le jẹ ko tubọ maa tẹsiwaju awọn iṣẹ rere to dawọ le, ati ibaṣepọ to dan mọnran nipa gbigbe awọn eeyan dide niluu Oko-Irese.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI