Nitori ẹja arọ to jigbe, wọn ju Taofik sẹwọn ọdun meji l'Osun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, August 17, 2025

Nitori ẹja arọ to jigbe, wọn ju Taofik sẹwọn ọdun meji l'Osun

Taofik

Solape Aduragbemi, Osun
 
Ọpọ awọn to wa nile ẹjọ Majisireeti tiluu Ila-Ọrangun nipinlẹ Ọṣun ni wọn la ẹnu wọn silẹ, ti wọn ko si fẹẹ le pa a de nigba ti ile-ẹjọ paṣẹ pe ki gendekunrin, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn kan lọ fi ẹwọn ọdun meji gbako gbara pẹlu iṣẹ aṣekara.
 
Olaniyan Taofik lorukọ ọmọkunrin naa, ẹni ti wọn lo ji ẹja arọ gbe lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun 2025.
 
Ko sohun meji to jẹ ki ọrọ idajọ naa maa ya ọpọ eeyan lẹnu, bi ko ṣe pe ile-ẹjọ naa ko faaye silẹ fun Taofik lati san owo itanran, leyi to le fi dipo ẹwọn rẹ.

Yatọ si ẹsun ole ti wọn fi kan Taofik, wọn lo wọnu ọgba ọlọgba, to si tun ba dukia onidukia jẹ kọja sisọ.
 
Awọn ẹṣọ aabo Amọtẹkun ni wọn rọwọ to Taofik, lẹyin ti wọn fi ẹjọ rẹ sun wi pe o wọnu oko oloko, to si lọ jale nibẹ.

Alakoso eto ofin fun Amọtẹkun, Oyedele Akintayo to foju Taofik ba ile-ẹjọ sọ pe inu oko Ọgbẹni Omidoyin Clement to wa lagbegbe Isale-Osun, Ila-Orangun, ni ọmọkunrin naa wọ lọna aitọ.

Lara awọn nnkan ti Akintayo sọ pe Taofik jigbe ninu oko naa ni Kokoo, irinṣẹ inu oko, ọgẹdẹ, ooomu ati ẹja aarọ ti ko tii ku, eyi ti apapọ owo rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna irinwo naira.
 
Yatọ si eyi, o ni Taofik tun ba ẹrọ ayaworan to pe ni CCTV ti wọn fi n wo ohun to n ṣẹlẹ ninu oko naa jẹ, eyi to pe owo rẹ ni ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira.
 
O sọ pe nibi ti Taofik ti n gbero lati ta awọn ohun to jigbe ni ọwọ palaba rẹ ti segi niluu Ila-Orangun.

Agbẹjọro naa fidi rẹ mulẹ pe nigba ti wọn n fọrọ wa Taofik lẹnu wo, o jẹwọ gbogbo iwa to ti hu, to si gba pe lotitọ loun jale naa, ati pe oun ko ṣẹṣẹ maa jale.

Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Onidajọ A.A. Ayeni sọ pe awọn ẹri toun ri gba nipa ẹsun ti wọn fi kan Taofik lo kọja ohun ti wọn le da ọwọ bo mọlẹ, to si gbọdọ jiya ẹṣẹ rẹ labẹ ofun ni abala kọkanlelọgọrin, ipin 390(9), ati 451 ninu iwe ọdaran tipinlẹ Osun ni ọdun 2002.

Onidajọ Ayeni sọ pe idajọ naa yoo kọ awọn yooku lọgbọn, bẹẹ si ni yoo tun daabo bo awọn nnkan oko awọn agbẹ, paapaa lawọn igberiko.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI