Ile gbigbe: Ijọba ipinlẹ Eko fi aami ẹyẹ da ileeṣẹ Adron Homes lọla - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, October 7, 2025

Ile gbigbe: Ijọba ipinlẹ Eko fi aami ẹyẹ da ileeṣẹ Adron Homes lọla


Ijọba ipinlẹ Eko labẹ iṣakoso Gomina Babajide Sanwo-Olu ti gbe oṣuba kare fun ileeṣẹ Adron Homes lori ipa ti wọn n ko ninu idagbasoke ile gbigbe ati okoowo dukia nipinlẹ naa.

Aami ẹyẹ naa lo fi ontẹ luu nipa akitiyan awọn alakoso ileeṣẹ naa lori idagbasoke agbegbe ati igberiko kaairi Naijiria nipa sisọ igbo di ilu.

Ẹka ileeṣẹ ijọba to n ri sọrọ ilana ile kikọ ati idagbasoke igberiko (Ministry of Physical Planning and Urban Development) lo fi aami ẹyẹ ọhun da Adron Homes lọla.

Ọjọ Aje, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹwaa, ọdun 2025 to jẹ ayajọ ayipada oju ọjọ lagbaye, eyi to waye l'Ekoo ni wọn ti gbe aami ẹyẹ naa le wọn lọwọ.

Ayẹyẹ tọdun yii ti wọn pe akori rẹ ni “Urban Crisis Response: Flooding in Focus”, ni wọn ṣe lati fi sọrọ lori iṣoro ati idojukọ nipa agbara ojo, ati ọna abayọ.

Nigba to n sọrọ, Kọmiṣanna ileeṣẹ naa, Ọmọwe Oluyinka Olumide, jẹ ko di mimọ pe awọn mọ ileeṣẹ Adron Homes gẹgẹ bi eyi to tayọ yatọ nipa mimu idagbasoke ba agbegbe ati igberiko.

Nigba to n gba aami ẹyẹ naa, alakoso agba, Arabinrin Adenike Ajobo, fi idunnu rẹ han, to si loun dupẹ pe ijọba ri akitiyan wọn, leyi to fi han pe iṣẹ wọn ko ja si asan. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI