Okonkwo to fẹẹ ko ibasun fọmọkunrin, ọmọ ọdun mẹẹdogun dero ile-ẹjọ l'Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, October 3, 2025

Okonkwo to fẹẹ ko ibasun fọmọkunrin, ọmọ ọdun mẹẹdogun dero ile-ẹjọ l'Ekoo

Bawọn eeyan ṣe n gbadura pe ki wọn ma ṣe rogun ikawọ-mọri, f'ẹsẹ janlẹ, iyẹn ko ṣiṣẹ rara fun gendekunrin ẹni ọdun mejidinlọgbọn kan, Okonkwo Chikwado nigba to bẹrẹ sii kawọ mọri niwaju ile ẹjọ, to si n f'ẹsẹ janlẹ wi pe oun ti ko sọwọ.

Ẹsun Ibalopọ ọkunrin si ọkunrin ni wọn fi kan Okonkwo niwaju ile-ẹjọ Majisireeti to wa lagbegbe Ikẹja nipinlẹ Eko, koda ọmọdekunrin, ọmọ ọdun mẹẹdogun ni wọn pe ọmọ to fẹẹ ba laṣepọ buruku naa.

Ojule keji, adugbo Asake to wa ni Ishashi nipinlẹ Eko ni wọn sọ pe Okonkwo n gbe.

Agbefọba, ASP Adegoke Ademigbuji, to foju rẹ ba ile-ẹjọ ṣalaye pe ile ti Okonkwo n gbe naa lo tan ọmọ ọhun wọ lọjọ kẹrinla, oṣu Keje, ọdun yii.

Niṣe ni wọn lo sọ pe oun fẹẹ ran ọmọ naa niṣẹ, lai mọ pe iṣẹ ibi to fẹẹ ṣe wa lọkan rẹ.

Wọn ni bọmọ naa ṣe wọnu yara rẹ, lo ti aare tilẹkun lẹyin, to si bẹrẹ sii ṣiṣẹ buruku ọhun

Onidajọ L. A. Owolabi ti wa paṣẹ pe ki Okonkwo ṣi wa lọgba ẹwọn Kirikiri titi di ọjọ kejilelogun, oṣu yii ti igbẹjọ miran yoo tun waye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI