O ma ṣe o! Kasnaty Sugar, gbajumọ sọrọsọrọ padanu baba rẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, October 7, 2025

O ma ṣe o! Kasnaty Sugar, gbajumọ sọrọsọrọ padanu baba rẹ


Titi di asiko yii ni iku Alaaji Adejojo to jẹ baba Kolawole Atanda Adejojo, ẹni tọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Kasnaty Sugar ṣi n jẹ kayeefi fọpọ awọn to gbọ.

Kasnaty Sugar funra rẹ lo kede iku baba rẹ laarọ oni, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee loju opo Facebook.

Nigba to n kede, o ni "ALHAJI ADEJOJO Inna Lila hi waina ilaehin rojeehun, baba mi ku laarọ oni........"


Ọpọ awọn ololufẹ ọkunrin naa ni wọn ti n ba a kẹdun latigba naa, ti wọn si n gbadura fun un.

Odu ni Kolawole Atanda Adejojo lagbo iṣẹ pedepede nipinlẹ Ogun, to si tun gbajumọ daadaa lori ayelujara.

Nigba to n kede isinku baba rẹ, o sọ pe Ọjọru, ọsẹ yii, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2025 ni wọn yoo sinku baba rẹ nilana musulumi ni itẹku Al-Sunah to wa ni Olomore Housing Estate, Abẹokuta.

Kasnaty jẹ ko di mimọ pe agogo mẹwaa aarọ ni wọn yoo sinku naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI