Òtítọ́ korò ló jẹ́ kí wọ́n máa fi ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ gbé mi lójoojúmọ́ - Adébutú - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, October 11, 2025

Òtítọ́ korò ló jẹ́ kí wọ́n máa fi ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ gbé mi lójoojúmọ́ - Adébutú


Oludije sipo gomina ipinlẹ Ogun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party, PDP, Ọnarebu Ọladipupọ Adebutu sọ pe nitori otitọ toun duro le lori ni awọn alakoso ijọba ṣe n fi ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ dunkooko mọ oun ni gbogbo igba.

Adebutu sọ pe lotitọ loun mọ pe otitọ koro jọjọ, ṣugbọn to ni gbogbo igba loun yoo maa sọ ọ, titi digba ti awọn alakoso ijọba yoo fi ṣe ohun to yẹ lati ṣe, ki araalu le jẹ mudunmudun eto iṣejọba awa-ara-wa.

Agba oloṣelu naa lo sọrọ yii nibi apejọ ọlọdọọdun (Annual Colloquium) ti ajọ NIPR, ẹka tipinlẹ Ogun ṣagbekalẹ rẹ niluu Abẹokuta, eyi ti wọn pe akori rẹ ni “Leadership and Reputation: The Role of Public Relations in Building Trust in Nigeria.”

Nigba to n sọrọ, o ni "Nigba ti mo de, mo ṣakiyesi alakoso ajọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ nibi, ṣugbọn mo nigbagbọ pe aṣoju wọn ṣi wa nitosi lati gbọ ohun ti mo fẹẹ sọ, o si ṣee pe wọn yoo tun ni ki wọn ranṣẹ pe mi bi mo ba sọrọ otitọ mi tan laipẹ.

"Wọn maa n sọ fun wa pe Naijiria yẹ ko jẹ olori nilẹ Afrika. Iṣoro olori ni a ni. O ṣeni laanu wi pe awọn adari wa ko wa ọjọ iwaju rere fun wa...

"Nigba ti awọn adari ba ti kuna, a maa rii pe niṣe la ba ara wa lorileede to ti kuna. Bawo lẹ ṣe fẹ ki wọn maa kọ orukọ yin lori ayelujara? Ṣe adari onijẹkujẹ ni?

"Ẹ ma gbagbe wi pe awọn ọmọ yin yoo ka iroyin yẹn lọjọ iwaju. A ko le sọrọ nipa ipo adari lai jẹ pe a sọrọ nipa ipo ati iṣakoso ijọba.

"Nko fẹẹ sọ ibi yii tabi ọrọ mi di agbegbe anfaani lati polongo, ṣugbọn otitọ mo n tẹnu mọ naa ni pe ipo adari kii ṣe ọna lati ko owo ilu jẹ.

“Ibanujẹ lo jẹ wi pe a ti sun orileede yii debi 'ka gba anfaani mu, ka jale, ka si salọ pẹlu ẹ'. Wọn ti ba ilana eto iṣejọba awa-ara-wa jẹ, iru ipo adari wo wa leyi, ati pe iru orukọ wo la n kọ silẹ fun orileede wa?

"Awa nibi ti a wa lonii nitori pe a ko ni ẹri ọkan. Irọyin ibanujẹ lo le sare tan kaakiri lorileede Naijiria. O le dun un gbọ lati le fi ta iroyin, ṣugbọn ẹ ma gbagbe pe o le ba nnkan jẹ kọja sisọ.

"Idi niyẹn to fi jẹ pe onikaluku wa la ni ojuṣe lati ṣe, ka tun ero wa pa, ka si tun ọna wa ṣe. Iṣakoso wa gbọdọ ni oju aanu fawọn araalu, mo si maa n lo oriṣiriṣi apẹrẹ.

"Nigba ti a ba ko owo to yẹ ka fi kọ ile iwosan jẹ, ẹnikẹni to ba ku nitori pe wọn ko jẹ anfaani ile iwosan naa, nitori pe a ti daa si apo ara wa, iru ẹjẹ awọn eeyan bẹẹ wa lọrun onitọhun. Ṣugbọn ṣa, a ṣi ni awọn adari ti wọn ni ibẹru Ọlọrun lọkan.

Alaga ẹgbẹ NIPR nipinlẹ Ogun, Arabinrin Oluwaṣeun Boye, nigba to n sọrọ, o ni pataki ni lati maa fi iwa ọmọluwabi ṣe ijọba fun ilọsiwaju ati ati idagbasoke ilu.

Lara awọn to tun wa nibẹ ni iyawo gomina ana nipinlẹ Ogun, Arabinrin Olufunshọ Amosun, Lanre Ogunlọwọ ti agbẹnusọ ọlọpaa, Ọmọlọla Odutọla ṣoju fun ati awọn miran.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI