Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti fidi rẹ mulẹ pe iṣakoso oun ko dawọ duro lati maa ro awọn ọdọ paapaa awọn agbẹ lagbara kaakiri ipinlẹ naa, ki eto ọrọ aje le tubọ maa ni itẹsiwaju.
Govs AbdulRazaq lo sọ eyi nibi ajọdun ọdun karundinlọgbọn ti ajọ Nigerian Institution of Agricultural Engineers (NIAE), ati ipatẹ ọja agbaye ti National Agricultural Machinery Exhibition, akọkọ iru rẹ to waye ni National Centre for Agricultural Mechanisation (NCAM), ilu Idofian, ijọba ibilẹ Ifelodun, ipinlẹ Kwara lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii.
Ipade gbogboogbo naa ti Gomina ipinlẹ Borno, Babagana Umara Zulum ko gbẹyin nibẹ lawọn akọṣẹmọṣẹ agbẹ ti peju, ti wọn si sọ awọn ọna abayọ si iṣoro ti wọn n koju.
Nibẹ ni Gomina AbdulRazaq ti fidi rẹ mulẹ pe iṣakoso oun tun ti gbe awọn ilana ati eto tuntun miran kalẹ lati ro awọn ọdọ, oniṣẹ iwadii ati olokoowo agbẹ lagbara, lati le ni ipa rere ti wọn yoo ko lawujọ, ki aabo to daju le wa lori awọn ounjẹ.
Gomina ṣalaye pe agbẹ to le ni ẹgbẹrun mẹwaa ni wọn ti jẹ ninu anfaani ti iṣakoso oun gbe kalẹ, nipa gbigba awọn ohun elo ati irinṣẹ inu oko bii katakata ati awọn nnkan miran lati mu ki iṣẹ naa rọrun.
Lara awọn to tun wa nibẹ ni minisita fọrọ eto iṣẹ agbẹ nilẹ Naijiria, Sẹnetọ Abubakar Kyari, atawọn miran.
Nigba to n sọrọ, Ọjọgbọn Babagana Umara Zulum to sọrọ idanilẹkọọ gbe oṣuba kare fun Gomina lori ipa to n ko lawujọ, paapaa lẹka eto iṣẹ agbẹ ọhun.

No comments:
Post a Comment