Itan tuntun: Ileeṣẹ Adron Homes ṣagbekalẹ idije ẹyin ori papa l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, November 16, 2025

Itan tuntun: Ileeṣẹ Adron Homes ṣagbekalẹ idije ẹyin ori papa l'Ogun


Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii lawọn eeyan ṣi n fi idunnu han si idije ẹyin ori papa ti ileeṣẹ Adron Homes ṣagbekalẹ rẹ nipinlẹ Ogun.

Igba akọkọ ree ti ileeṣẹ Adron Homes to gbajumọ ninu ilẹ ati dukia tita nilẹ Naijiria yoo maa ṣagbekalẹ eto ere idaraya bayii.

Ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2025 ti a wa yii ni awọn alakoso ileeṣẹ naa tun gbọna ara yọ lori agbekalẹ eto ọhun ti wọn pe ni Adron Cup Golf Tournament fun igba akọkọ.

Inu ọgba Elephant Cement Golf Club, ti Remo, eyi to wa niluu Sagamu, ipinlẹ Ogun ni idije naa ti waye, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Gbogbo awọn ololufẹ ere idaraya ti ẹyin ori papa, iyẹn Golf kaakiri ileeṣẹ ati ọjọgbọn ni wọn fi ara jin fun eto naa to kun fun igbadun ara.

Nigba to n ṣiṣọ loju eto ọhun, Aarẹ Adetola Emmanuelking to jẹ alaṣẹ ati oludasilẹ sọ pe igba akọkọ ree ti idije naa yoo waye, ati pe bi wọn yoo ti maa ṣe e lọdọọdun niyẹn.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ni ibẹrẹ ọdun yii ni Aarẹ EmmanuelKing gba aami ẹyẹ ti wọn pe ni "Nigeria’s Noble Golfer Award", nitori awọn ipa manigbagbe to n ko lẹka ere idaraya naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI