Ileeṣẹ ologun inu ofurufuru tilẹ Naijiria, iyẹn Nigerian Air Force (NAF) ti sọ pe awọn ti ṣe ikọlu alaragbayida si ibudo awọn agbesunmọmi kaakiri ẹkun Ariwa orileede naa.
NAF sọ pe awọn ti ṣe ikọlu iparun fawọn ọmọ ẹgbẹ agbesunmọmi ti Islamic State of West Africa Province (ISWAP) to wa ni Mallam Fatori ati Shuwaram, nipinlẹ Borno.
Bakan naa ni wọn tun sọ pe awọn tun ṣe ikọlu iparun si awọn babdiiti ti wọn agbegbe Garin Dandi ati Chigogo nipinlẹ Kwara.
Yatọ si awọn ipinlẹ naa, NAF tun jẹ ko di mimọ pe ikọlu iparun naa tun tẹsiwaju lori oke Zango to wa nijọba ibilẹ Kankara, ipinlẹ Katsina.
Ninu atẹjade ti alakoso eto iroyin, Commodore Ehimen Ejodame fi sita, o ṣalaye pe ikọlu iparun naa ṣe pataki, lati le jẹ ki ọrọ eyo aabo tubọ kẹsẹjare.
Ejodame fidi rẹ mulẹ pe iṣẹ ajumọṣe ni ikọlu iparun naa, nitori pe igbesẹ naa ko ṣẹyin awọn ikọ bii Operation HADIN KAI ati Operation FANSAN YAMMA, pẹlu erongba lati pa gbogbo awọn ọdaran run kaakiri ẹkun Ariwa Naijiria.

No comments:
Post a Comment