Alaṣẹ Adron Homes gbe oṣuba kare fawọn oniṣowo dukia nipinlẹ Oyo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, November 6, 2025

Alaṣẹ Adron Homes gbe oṣuba kare fawọn oniṣowo dukia nipinlẹ Oyo

Aarẹ Adetola EmmanuelKing to jẹ alaṣẹ agba ati oludasilẹ ileeṣẹ Adron Homes to n ri sọrọ ilẹ ati dukia kaakiri Naijiria ti rọ gbogbo awọn oniṣowo dukia nipinlẹ Oyo lati tẹsiwaju nipa titẹle ilana, fun idagbasoke.

Aarẹ EmmanuelKing gbe oṣuba kare fun ijọba ijọba ipinlẹ Oyo lori atunto ti wọn ṣe lẹka eto okoowo dukia, iyẹn Real Estate, to si ṣapejuwe ipinlẹ naa gẹgẹ bi ilẹ “itan, okoowo ati anfaani atigbadegba.”

Oludasilẹ naa sọrọ wọnyi lasiko to sọrọ nibi eto awọn oniṣowo dukia to n waye lọdọọdun, ti ọdun 2025 to waye niluu Ibadan.

Eto ọhun ti wọn pe akori rẹ ni “Real Estate and Economic Development in Oyo State: Strategies for Success,” lo kun fun ọpọ awọn alẹnulọrọ lẹka eto okoowo dukia kaakiri Naijiria, ti wọn si mẹnuba awọn ipenija ati ọna abayọ, pẹlu awọn igbesẹ tuntun.

Aarẹ EmmanuelKing gbe oriyin fuj Gomina Seyi Makinde lori agbekalẹ ṣiṣe-n-tẹle lati jẹ ki ohun gbogbo lọ letoleto.

Ṣaaju asiko yii ni olori ile igbimọ aṣofin Oyo, Ọnarebu Adebo Ogundoyin jẹ ko di mimọ pe ijọba ti fi ara jin fun igbasoke eka naa, lati le fa awọn olokoowo wọle, paapaa lati le jẹ ki abojuto to pe ye wa fun ile kikọ ni ibamu pẹlu ilana ati agbekalẹ.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI