Olufolake, iyawo Gomina AbdulRazaq sọ idi to fi ṣe pataki lati tete ṣabojuto aisan jẹjẹrẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, November 11, 2025

Olufolake, iyawo Gomina AbdulRazaq sọ idi to fi ṣe pataki lati tete ṣabojuto aisan jẹjẹrẹ


Lati saami ayẹyẹ ayajọ ọjọ aarun jẹjẹrẹ lagbaye, iyawo gomina ipinlẹ Kwara, Arabinrin Olufolake AbdulRazaq ti rọ awọn araalu lati maa ṣ'ayẹwo ara wọn loorekoore fun arun jẹjẹrẹ.

AbdulRazaq sọ pe bi awọn eeyan ba tete kofiri arun naa ni ara, anfaani itọju to pe ye wa lati dena rẹ, ko ma ba a ṣe akoba.

O rọ araalu lati ṣamulo anfaani ayẹwo ọfẹ tijọba ṣagbekalẹ rẹ lati mu opin de ba arun jẹjẹrẹ naa.

Olufolake AbdulRazaq to tun jẹ alaga igbimọ ẹgbẹ awọn iyawo gomina lorileede Naijiria sọ eyi di mimọ nibi ifilọlẹ lati saami ayẹyẹ ayajọ ọjọ aisan jẹjẹrẹ ọmu lagbaye.

Nibẹ lo ti gbe oṣuba kare fun ijọba ipinlẹ naa lori igbesẹ lati mu ọrọ ilera araalu lọkunkundun.

Nigba toun naa n sọrọ ikini rẹ, alaga igbimọ to n ri sọrọ eto ilera, Ọnarebu Seun Ogunniyi, jẹ ko di mimọ pe ọna abayọ wa lati dena aisan jẹjẹrẹ, to si gba awọn eeyan lamọran lati maa yọju s'awọn eleto ilera fun itọju to pe ye.









No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI