Ijọba ipinlẹ Kwara ti sọ fun gbogbo araalu lati ma ṣe gba iroyin ẹlẹjẹ to n lo kaakiri igboro nipa wi pe awọn oṣiṣẹ ologun rọwọ to awọn agbesunmọmi nijọba ibilẹ Ifelodun.
Wọn ni awọn alaimọkan ti wọn n gbero lati ko ibẹru sọkan awọn araalu ni wọn n gbe iroyin ti kii ṣe otitọ naa kaakiri ori ayelujara.
Ijọba ni ko sibi kankan ti awọn agbesunmọmi ti ṣọṣẹ, depodepo wi pe awọn ologun yoo rọwọ to wọn.
Atejade ti Bolanle Olukoju to jẹ Kọmiṣanna feto iroyin nipinlẹ naa fi sita lọjọ Aiku to kọja, fidi rẹ mulẹ pe iroyin ẹlẹjẹ lasan ni.
O wa rọ awọn eeyan lati ma ṣe foya nitori pe eto aabo nipinlẹ Kwara lasiko yii, digbi lo wa.
No comments:
Post a Comment