Ẹgbẹ awọn oniṣegun oyinbo fi aami ẹyẹ da Gomina AbdulRazaq lọla ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, December 16, 2025

Ẹgbẹ awọn oniṣegun oyinbo fi aami ẹyẹ da Gomina AbdulRazaq lọla ni Kwara


Ẹgbẹ awọn oniṣegun oyinbo nilẹ Naijiria, NMA tun ti fi aami ẹyẹ nla da Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara lọla.

Wọn ni ipa to n ko lori eto ilera ati idagbasoke ọmọniyan nipinlẹ naa ko lafiwe.

NMA lo fi aami ẹyẹ nla na da gomina ọhun lọla nibi ipade awọn alakoso ẹgbẹ naa, eyi to waye niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.

Dokita Amina Ahmed El-Imam to jẹ Kọmiṣanna feto ilera ni Kwara, ẹni to ṣoju Gomina ipinlẹ ọhun fi imọriri rẹ han, to si ni ipenija ni aami ẹyẹ naa jẹ fun gomina lati ṣe ju ti tẹlẹ lọ.

O gbe oriyin fawọn alakoso ẹgbẹ NMA lori bi wọn ko ṣe gboju fo awọn akitiyan gomina lati mu idagbasoke ati itẹsiwaju ba eto ilera nipinlẹ Kwara

Ọmọwe El-Imam jẹ ko di mimọ pe oniruuru akọsilẹ to laami laaka, ti ko ṣee fọwọ rọ sẹyin ni ijọba Kwara ti ṣe, nipa jijẹ ki araalu ni anfaani si eto ilera alailafiwe, ati bo ṣe mu ọrọ igbayegbadun awọn oṣiṣẹ lẹka eto ilera lọkunkundun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI