Fun igba kẹta, Kwara gbegba oroke lẹka eto ilera alabọde - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, December 14, 2025

Fun igba kẹta, Kwara gbegba oroke lẹka eto ilera alabọde


Ipinlẹ Kwara la gbọ pe wọn ti gba aami ẹyẹ nla tuntun, gẹgẹ bi ipinlẹ to ṣe daadaa julọ lẹka eto ilera alabọde, iyẹn lẹkun Aarin Gbungbun Ariwa ilẹ Naijiria.

Nibi eto ti wọn pe akori rẹ ni 2025 Primary Health Care (PHC) Leadership Challenge, ni ipinlẹ Kwara ti gbarada mọ awọn akẹgbẹ wọn lọwọ.

Oriire nla yii la gbọ pe wọn yoo jẹ igbakẹta lera wọn ti wọn yoo gba a, leyi to fi aridaju han pe wọn ko rẹwẹsi.

Aami ẹyẹ naa lo tun wa pẹlu anfaani ẹgbẹrun lọna irinwo dọla ($400,000), lati fi ṣe agbelarugẹ fun eto iwosan alabọde fawọn araalu, ni ibamu pẹlu ilana ajọ United Nations Children’s Fund (UNICEF) ati ti ẹgbẹ awọn gomina ilẹ Naijiria, (NGF).

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI