Ipinlẹ Kwara wọ ẹwu iyi pẹlu ayipada ọtun lasiko AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, December 14, 2025

Ipinlẹ Kwara wọ ẹwu iyi pẹlu ayipada ọtun lasiko AbdulRazaq


Adura nla ni awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Kwara lapapọ n gba fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lasiko yii, lori bo ṣe n sọ ipinlẹ naa di ti igbalode, leyi to dun un wo loju.

A gbọ pe ọpọ awọn to ba ti de ipinlẹ naa ti pẹ, afaimọ ni ki wọn ma pada ṣina lasiko ti wọn ba tun pada sibẹ, nitori awọn ayipada ọtun to ti wọle.

Ninu awọn aworan ti Akewejẹ Olayinka Fafoluyi to jẹ amugbalẹgbẹ pataki fun gomina lori eto iroyin igbalode fi soju opo Facebook rẹ, o ni "ayipada n de ba ipinlẹ Kwara lọna ti awọn eeyan le ri, ti wọn le ni imọlara rẹ, ati ti wọn tun le nifẹ si".

"Akitiyan Gomina AbdulRahman AbdulRazaq n jẹ ki ipinlẹ naa wa ni imọtoto, ko rẹwa, ko si tun ni eto daadaa."

O tẹsiwaju pe gbogbo araalu patapata ni ori wọn n wu si ayipada ọtun, to n jẹ ki ilu wọn dun un wo loju, ti wọn si le fọwọ rẹ sọya fun awọn alejo wi pe awọn ti ni agbegbe to dara fun eto irin-ajo afẹ.

Diẹ ree lara awọn aworan bi ipinlẹ naa ṣe ri...

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI