Alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited nilẹ Naijiria, Aarẹ Adetola EmmanuelKing ti ba Gomina ati gbogbo ọmọ ipinlẹ Oyo lapapọ yọ fun ti ayẹyẹ aadọta ọdun ti wọn da ipinlẹ naa silẹ.
Aarẹ EmmanuelKing nigba to n ki awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa yọ ninu atẹjade to fi sita lọjọ Abamẹta tii ṣe Satide, o ni ayẹyẹ naa ṣafihan ifarada, iwuri nipa aṣa ati itẹsiwaju alailafiwe.
O ni latigba ti wọn ti da ipinlẹ naa silẹ, Oyo ti jẹ ọkan gboogi ninu ipinlẹ to n ṣe iranwọ fun itẹsiwaju eto ọrọ aje, idagbasoke aṣa ati agbegbe to nifẹ si okoowo, eto ẹkọ ati imọ ẹrọ.
Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, Aarẹ EmmanuelKing sọ pe asiko lati ṣe aṣaro ati atunṣe ifarajin ijọba, ileeṣẹ aladani, awọn ọba alaye ati araalu lati le mu aṣeyọri ba ipinlẹ naa siwaju sii.
Aarẹ EmmanuelKing wa gbe oṣuba kare fun ijọba ipinlẹ naa lori awọn akanṣe iṣẹ to n lọ kaakiri nipa iṣẹ ilu, imugbooro eto ọrọ aje, ati idagbasoke ọmọniyan.
O ni agbajọwọ ni iṣẹ idagbasoke jẹ, ti gbogbo araalu ti gbọdọ fọwọsowọpọ pẹlu ijọba lati mu itẹsiwaju ba ipinlẹ naa.
No comments:
Post a Comment