Eeyan kan ku, awọn mẹjọ farapa ninu ijamba ọkọ alajapa l’Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, January 30, 2026

Eeyan kan ku, awọn mẹjọ farapa ninu ijamba ọkọ alajapa l’Ogun

Bko sẹni to le mu ẹkun mọra nibi ijamba ọkọ to fẹmi eeyan kan ṣofo, ti awọn ti ko din ni mẹjọ si farapa yannayanna lopopona marosẹ Eko si Ibadan, ipinlẹ Ogun.

Ọjọru, ọsẹ yii la gbọ pe ijamba naa waye lagbegbe Ṣaapade to wa ni marosẹ Eko si Ibadan naa, gẹgẹ bi agbẹnusọ ileeṣẹ to n bojuto igbokegbodo ọkọ nipinlẹ naa, Babatunde Akinbiyi ṣe ṣalaye f’awọn akọroyin niluu Abẹokuta.

Akinbiyi nigba to n ṣalaye, o ni aarọ kutu ọjọ naa ni ijamba naa waye, to si ni awakọ tirela alajapa kan to ko awọn nnkan ere inu oko lo ṣokunfa ijamba naa.

O sọ pe niṣe ni awakọ naa gbagbe sun lọ nibi to ti n wa tirela lo lopopona marosẹ, to si ṣe bẹẹ lọ ko sinu ọgbun kan

“Ijamba ọkọ kan lo ṣẹlẹ lagbegbe Uncle Abbey Block Industry to sunmọ agbegbe Iṣara-Rẹmọ si afara Ẹrimọbi to wa loju ọna marosẹ Ekoo si Ibadan.

“Ọkọ tirela Volvo kan ti ko ni nọmba idanimọ lo fa ijamba ọhun. Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni awakọ naa sunlọ nidi ọkọ wiwa, to si lọ ko sinu koto ọgbun.

“Awọn ọkanla ni wọn wa ninu ọkọ tirela alajapa naa. Ọkunrin kan lo ku ninu wọn, nigba ti awọn mẹjọ miran farapa,” Akinbiyi ṣalaye.

O sọ pe gbogbo awọn to farapa naa ni wọn ti ko lọ sile iwosan to wa nitosi fun itọju, nigba ti awọn fa oku ati ẹnikan toun ko farapa le awọn ẹgbẹ oni tirela lọwọ.

“Awọn mẹjọ to farapa la ko lọ sile iwosan Victory to wa ni Ogere-Rẹmọ fun itọju, nigba ti a fa oku naa, ati ẹnikan ti ko farapa le awọn ẹgbẹ oni tirela lọwọ,” Akinbiyi fidi rẹ mulẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI