Gbogbo eto lo ti pari bayii fun eto ayẹyẹ ikẹkọọgboye fasiti ọgbin to wa niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, iyẹn Federal University of Agriculture (FUNAAB) lati waye.
Opin ọsẹ ti a wa yii ni aṣekagba eto ayẹyẹ naa, ẹlẹkẹtalelọgbọn iru rẹ yoo waye ninu ọgba fasiti ọhun to wa ni Alabata, ijọba ibilẹ Ọdẹda.
Ayẹyẹ naa ti wọn tun fẹẹ fi ṣe ifilọlẹ awọn akanṣe iṣẹ idagbasoke ni yoo kun fun ọpọ awọn Ọjọgbọn ati alẹnulọrọ lawujọ kaakiri Naijiria ati lagbaye.
Nigba to n sọrọ nibi ipade awọn akọroyin to waye l'Ọjọru ana, Giwa fasiti naa, Ọjọgbọn Oluṣọla Babatunde Kẹhinde jẹ ko di mimọ pe ẹgbẹrun mẹrin le diẹ (4,141) ni gbogbo awọn akẹkọọ ti wọn yoo bọ sọja iṣẹ kaakiri agbaye.
Ọjọgbọn Kẹhinde sọ pe oniruuru aṣeyọri lo ti ba wọn ni fasiti naa laaarin ọdun kan si asiko yii, to si ni lara rẹ ni ti ina to n lo oorun, iyẹn Solar ti awọn ṣe sinu ọgba naa.
O ni owo ti awọn ileeṣẹ mọnamọna n mu wa fun wọn kọja agbara wọn, pẹlu bi wọn ṣe n yọ ina ọhun lo to, idi ree yo lawọn fi pinnu lati wa ọna abayọ ọlọjọ pipẹ.
Ọjọgbọn Kẹhinde ṣalaye pe owo ti ko din ni miliọnu marun-un naira ni awọn ileeṣẹ mọnamọna maa n fun wọn loṣooṣu, pẹlu bi wọn ṣe n mu adinku ba gbogbo ohun ti wọn n fi ina mọnamọna ṣe ninu ọgba wọn, to si ni eyi ti fẹẹ maa kọja agbara wọn.
Siwaju sii lo jẹ ko di mimọ pe owo ti awọn n na lori ina mọnamọna laaarin ọdun kan kọja apapọ owo tijọba apapọ n fun wọn lọdun kan lọ, to si lo ku diẹ kaato, idi pataki to ni awọn fi ronu nipa ina to n lo oorun (solar), eyi ti agbara rẹ jẹ mẹgawaati mẹta (3MW), to fidi rẹ mulẹ pe aṣeyọri naa waye nipa iranlọwọ banki agbaye.
Bakan naa lo ni awọn ifarajin to n mu aṣeyọri to lọọrin wa ni gbogbo igba lo fa a, ti ajọ TETFund fi forukọ wọn sinu awọn fasiti ti yoo jẹ anfaani eto ẹkọ ọfẹ fawọn oṣiṣẹ wọn, eyi to pe ni "2025 TETFund Scholarship for Academic Staff" ni ẹka fasiti ọgbin.
O ni lara ifarajin wọn lati maa pese awọn akẹkọọ to dantọ, ti wọn si wulo lawujọ, lo fa a ki ajọ NUC da buwọ lu ẹka ikẹkọọ tuntun ti wọn ti fagile lawọn fasiti ọgbin tẹlẹ pada fun wọn, iyẹn awọn ikẹkọọ bii, Accounting, Banking and Finance, Business Administration, Economics ati awọn miran.
Bẹẹ lo ni ẹka ikẹkọọ mẹrinlelogoji ni awọn n ṣe bayii ni fasiti wọn, lara rẹ si ni: Wildlife and Ecotourism Management, Forestry Resource Management, Hydrology and Water Resources Management, Climate Science and Agricultural Meteorology, Cooperative Studies and Development Studies ati bẹẹ bẹẹ lọ.
No comments:
Post a Comment