Wo bi o ṣe le jẹ anfaani dukia olowo pọọku nileeṣẹ Adron Homes lasiko Falẹntaini, pẹlu oniruuru ẹbun ọfẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 29, 2026

Wo bi o ṣe le jẹ anfaani dukia olowo pọọku nileeṣẹ Adron Homes lasiko Falẹntaini, pẹlu oniruuru ẹbun ọfẹ

Lojuna lati fi ifẹ han si gbogbo eniyan, paapaa awọn onibara tuntun lasiko ayajọ ololufẹ to n bọ lọna, iyẹn Falẹntaini, ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited ti ṣagbekalẹ anfaani ọtun ti ko wọpọ fun gbogbo awọn onibara wọn.

Yatọ si anfaani tuntun yii, awọn ẹbun oriṣiriṣi lo tun wa nilẹ fun awọn onibara to ba ba wọn dowopọ laaarin asiko yii si asiko ayajọ ololufẹ.

Agbekalẹ anfaani naa ti wọn pe ni Ifẹ fun Ifẹ “Love for Love” ni wọn gbe kalẹ lati fi jẹ ki awọn araalu fi ifẹ han si ara wọn nipa ile gbigbe.

Ninu atẹjade ti awọn alakoso ileeṣẹ naa fi sita l'Ọjọbọ, wọn jẹ ko di mimọ pe eto naa yoo fun awọn onibara ni anfaani lati san owo diẹ diẹ, ti wọn yoo si tun gba oriṣiriṣi ẹbun to jọju, lẹyin ti wọn ba ni dukia.

"Anfaani yii yoo wa titi asiko ayajọ ololufẹ ni gbogbo ibi ti ileeṣẹ Adron Homes wa kaakiri ilẹ Naijiria," awọn alakoso naa sọ bẹẹ.

Nigba to n gba ẹnu ileeṣẹ naa sọrọ, alakoso agba, Arabinrin Adenike Ajobo apapo awọn ṣagbekalẹ eto naa lati le fun awọn eeyan ni iwuri, ati erongba lati kuro lẹni to n fi ẹbun kekeekee tọrẹ si ẹbun to jọju bii dukia ilẹ ati ile, eyi ti wọn yoo lo titi lai.

"Labẹ agbekalẹ eto yii, awọn onibara to ba san ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira, yoo gba akara oyinbo, ṣokoleeti ati ọti waini; awọn onibara to ba san ẹgbẹrun lọna igba naira, wọn yoo gba baagi ẹbun (hamper); nigba ti awọn onibara to ba san idaji miliọnu naira yoo gba baagi ẹbun naa pẹlu akara oyinbo," Arabinrin Ajobo ṣalaye.

Bakan naa lo fidi rẹ mulẹ pe onibara to ba san miliọnu kan naira yoo gba foonu Samsung to ba wu wọn, tabi ki wọn gba baagi ẹbun ati akara oyinbo.

O tẹsiwaju pe bi owo ti onibara ba san ba ṣe pọ to, naa ni ẹbun ti wọn yoo gba yoo ṣe pọ to.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI