Alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited lorileede Naijiria, Aarẹ Adetola Emmanuel-King ti sọ pe ni gbogbo igba loun yoo maa lo ileeṣẹ oun lati ṣe agbelarugẹ fun aṣa ati iṣẹṣe ilẹ Yoruba.
Aarẹ EmmanuelKing lo sọrọ yii lasiko abẹwo to ṣe lọ si aafin Ọọni Ile-Ifẹ nipinlẹ Osun lọdọ Ọba Adeyẹye Enitan Ogunwusi.
Nibẹ lo ti ṣalaye pe oun nifẹ si ọrọ ero aṣa ati iṣẹṣe toun si maa n bọwọ fun oniruuru aṣa awọn ẹya to wa ni Naijiria.
O ni ibaṣepọ ileeṣẹ Adron Homes pẹlu awọn ọba alaye ko duro si ilẹ Yoruba nikan, bi ko ṣe gbogbo ẹya to wa kaakiri Naijiria fun igbelarugẹ.
O wa sọ pe gbogbo igba ni ileeṣẹ oun yoo maa ṣatilẹyin fun awọn ori ade lati gbe aṣa ati iṣẹṣe ilẹ wọn larugẹ.
No comments:
Post a Comment